Ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta fiku ṣefa jẹ, ọlọpaa ni wọn doju ija kọ

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, ti sọ pe mẹta lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to n da alaafia agbegbe, Ahoada, nijọba ibilẹ, Ahoada, nipinlẹ Rivers, laamu ni wọn ti fiku ṣefajẹ bayii.

Alukoro ileeṣẹ awọn ọlọpaa nipnlẹ naa, Abilekọ Grace Iringe Koko, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin kan lọjọ, Aiku, Sannde ọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Awọn kan ti wọn wa nitosi nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan n gbena woju ara wọn nitori ipo ni wọn waa fọrọ ọhun to awọn agbofinro leti, tawọn ọlọpaa si tete ta mọra lati lọọ fọwọ ofin mu gbogbo ẹni ti wọn ba ri nibẹ.

Gbara ti wọn de ibi tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mejeeji naa ti n bara wọn ja ni wọn ti koju awọn ọlọpaa, ṣugbọn agbara awọn agbofinro yii pọ ju tawon ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lọ, eyi to mu ki ibọn awọn ọlọpaa ba mẹta lara wọn nibi ti ko daa, to si ṣeku pa wọn loju-ẹsẹ.

Meji lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ibọn awọn ọlọpaa yii pa ni, Oloogbe Azhinibudu Biko, ẹni tawọn eeyan mọ si Yankee ati Gboka Odoi. Awọn mejeeji yii ni wọn fẹsun kan pe wọn maa n figba gbogbo da awọn araalu agbegbe naa laamu.

Bakan naa ni kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa ti sọ pe oun ko ni i fọwọ kekere mu ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun rara nipnlẹ naa mọ bayii, o ni pe ki wọn kuro nipinlẹ oun lo maa daa ju, tabi ki wọn jawọ ninu ṣiṣe ẹgbẹ okunkun naa.

Leave a Reply