Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọlalẹyẹ Quadri, to jẹ akẹkọọ Poli ipinlẹ Kwara, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Quadri ṣalaye fun ALAROYE pe ọmọ bibi ilu Ẹdẹ loun, sọ pe ọdun 2016 ni ẹnikan to jẹ ‘Area Brother’ oun mu oun wọ ẹgbẹ okunkun torukọ wọn n jẹ Ẹiyẹ.
O ni lasiko ti awọn ọlọpaa da oun duro loju ọna niluu Oṣogbo ni wọn gba foonu oun, ti wọn si ri oriiṣiriṣii fọto ti oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ naa ya, idi si niyẹn ti wọn fi mu oun.
Quadri fi kun ọrọ rẹ pe awọn ki i fi ẹgbẹ naa huwa buburu bi ko ṣe ki awọn kora jọ lati mu ọti, ki awọn si fa siga.
Ṣugbọn Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Ọlalẹyẹ Falẹyẹ, sọ pe awọn ba ibọn ilewọ kan pẹlu ọta lọwọ Quadri, ọmọ ọgbọn ọdun naa.
Ọlalẹyẹ sọ pe agbegbe Islahudeen/Ayekalẹ, ni ọwọ ti tẹ afurasi naa lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. O ni ọmọkunrin naa jẹwọ pe ọkan lara awọn alabaṣiṣẹpọ Rasheed Ọkọọlu, ogbologboo tọọgi ti awọn ọlọpaa fẹsun kan pe o n da ilu Ẹdẹ ati Oṣogbo ru ni, ki ọwọ to tẹ ẹ.
Ọga ọlọpaa fi kun ọrọ rẹ pe Quadri tun jẹwọ lọdọ awọn pe oun ti lọwọ ninu oniruuru iṣekupani to waye niluu Oṣogbo ati agbegbe rẹ lọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lẹyin iku Taju Rabiu ti inagijẹ rẹ n jẹ Spanner.
O ni ti gbogbo iwadii ba ti pari ni Qaudri yoo foju bale ẹjọ.