Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Orukọ awọn ọmọlẹyin gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, meji lo wa lara awọn orukọ marundinlọgbọn ti Gomina Ademọla Adeleke fi ṣọwọ sile-igbimọ aṣofin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun yii, gẹgẹ bii kọmiṣanna.
Lara awọn igun ẹgbẹ APC ti wọn n pe ni ‘The Osun Progressives’ ni Barisita Kọlapọ Alimi ati Ọgbẹni Biyi Anthony Ọdunlade.
Awọn orukọ yooku ni Barr. Oladoṣu Babatunde, Ọmọọba Bayọ Ogungbangbe, Ọgbẹni Sẹsan Epharaim Oyedele, Ọgbẹni Sọji Ajeigbe, Ọgbẹni Moshood Ọlalekan Ọlagunju.
Ọnarebu George Alabi, Ọnarebu Sunday Olufẹmi Oroniyi, Ọgbẹni Abiọdun Bankọle Ojo, Dokita Baṣiru Tokunbọ Salami, Ogbẹni Morufu Ayọfẹ, Ọgbẹni Ṣọla Ogungbile ati Rẹfrẹndi Bunmi Jẹnyọ.
Awọn yooku ni Arabinrin Ayọ Awolọwọ, Barisita Wọle Jimi Bada, Ọnarebu Dipọ Eluwọle, Alhaji Rasheed Aderibigbe, Ọjọgbọn Mọrufu Ademọla Adeleke, Ọgbẹni Adeyẹmọ Festus Ademọla, Barisita Jọla Akintọla, Ọnarebu Mayọwa Adejọrin, Iyaafin Adenikẹ Folashade Adeleke, Ọgbẹni Tọla Faṣeru ati Alhaji Ganiyu Ayọbami Ọlaoluwa.
Gẹgẹ bi olori ile, Rt. Ọnarebu Wale Ẹgbẹdun, ṣe wi, o ni logan ni ayẹwo yoo bẹrẹ fun awọn kọmiṣanna naa.