Ọmọ iya meji ti rewele o: EFCC mu tẹgbọn-taburo to n ṣe Yahoo

Adeoye Adewale

Ọwọ ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku mọku ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC) ti tẹ mejila lara awọn ọmọ Yahoo kan to jẹ pe ilu Abuja ni wọn fi ṣe ibujokoo wọn, ṣugbọn eyi to buru ju nibẹ ni pe tẹgbọn taburo wa ninu awọn ti wọn mu yii. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii, lọwọ tẹ wọn lẹnu iṣẹ ibi ti wọn n ṣe naa. Lara awọn ọmọ Yahoo ọhun tọwọ tẹ, ti wọn si n ran awọn ajọ EFCC naa lọwọ ninu iwadii wọn ọhun ni tẹgbọn-taburo meji yii wa.

ALAROYE gbọ pe  lasiko tawọn oṣiṣẹ ajọ ọhun n lọ kaakiri aarin ilu naa, ti wọn si n fọwọ ofin mu awọn ọmọ Yahoo ni ọwọ tẹ awọn eeyan yii.

Awọn agbegbe ti awọn agbefọba naa ti fọwọ ofin mu wọn:  Gwarimpa, Katampe ati Kari, niluu Abuja kan naa.

Lara awọn to ti wa lakata wọn bayii ni:  Maxwell Nwanno, Kingsley Nwanono, Owoh Chinedu, Ricaldo Francis, Thomas Pante, Chika Okoh, Okusun Destiny, Richard Anthony, Jonathan Victor, Ekulonor ati Kingsley Henry.

Foonu igbalode bii ogun, ẹrọ kọmputa agbeletan mẹsan-an, mọto Mercedes Benz mẹta, mọto Toyota Avalon kan ati mọto Lexus 330 kan ni wọn gba lọwọ awọn ọmọ Yahoo ọhun.

EFCC ti sọ pe gbara tawọn ba ti pari iwadii awọn nipa awọn ọdaran naa lawọn maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply