Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọ tuntun jojolo kan lo ku lojiji ninu ija buruku to waye laarin awọn obi rẹ, Ọgbẹni Ekene Ijokun ati Abilekọ Rose Ijokun, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Iṣẹlẹ yii waye lagbegbe kan ti wọn n pe ni Ẹlẹyọwo, to wa loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to jẹ alabaagbe tọkọ-taya ọhun pe iwa lilu obinrin bii ẹni lu ẹgusi bara ti di baraku fun Ekene to jẹ baba ọmọ tuntun naa.
O ni bo ṣe n lu iyawo rẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn ọhun ni alubami ree lasiko to fi wa ninu oyun, iwa buburu yii lo si tun tẹsiwaju lẹyin ti obìnrin naa bimọ tan, eyi to pada yọri si iku airotẹlẹ fun ọmọ ikoko ọhun.
O ni ọrọ ti ko to nnkan lo dá ija silẹ laarin tọkọ-taya naa lọjọ ta a n sọrọ rẹ yii, gbolohun aṣọ ni wọn kọkọ fi bẹrẹ gẹgẹ bii iṣe wọn, ko pẹ rara ti ọrọ tun fi di ti igbaju igbamu ti kẹrikẹri n ba rode.
Ibi tí wọn ti n ja lọwọ ni aburo iyawo ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ti sare lọọ ba ẹgbọn rẹ, to si fa ọmọ tuntun to pọn naa jade lẹyin rẹ ki wọn ma baa ṣe e leṣe.
Bo ṣe fẹ ẹ tẹ ọmọ naa sori ibusun lo ṣakiyesi pe ko mi mọ, loju-ẹsẹ lo ni obinrin naa sare pe awọn araadugbo, tí wọn sì jọ gbe ọmọ ọsẹ meji yìí lọ sileewosan alabọọde kan to wa nitosi ile wọn, níbi tí wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ti ku.
Tọkọ-taya naa la gbọ pe wọn ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo lori ipa ti wọn ko lori ọrọ iku ọmọ wọn.