Ọmọ ọran kan ree o, David gbẹmi baba ẹ, o loun maa n lalaa ri i loju oorun oun

Adewale Adeoye

Nitori bo ṣe fi ọmọ-odo fọ baba rẹ lori titi tiyẹn fi ku pẹlu ẹsun pe niṣe loun maa n lalaa ri baba naa nigba gbogbo, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti mu ọdọmọkunrin kan, David Felix, ẹni ogun ọdun kan, to n gbe lagbegbe Madakiya, nijọba ibilẹ Zango Kataf, nipinlẹ Kaduna.

ALAROYE gbọ pe ẹsun ti afurasi ọdaran ọhun fi kan baba rẹ ni pe baba oun maa n pa awọ da, ti yoo si di ẹyẹ abami nla kan, ti yoo yọ s’oun loju oorun, ta a si fẹẹ ṣe ohun nijamba.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, A.S.P Mansir Hassan, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ yii, ṣalaye lakooko ti wọn n ṣafihan ọdọmọkunrin naa pe ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye, ti ọwọ si pada tẹ David lẹyin to gbẹmi baba rẹ tan.

O ni, ‘A ti fọwọ ofin mu David bayii, o si ti jẹwọ pe loootọ, oun loun pa baba oun sinu ile. Ẹsun pe baba naa maa n pa awọ da, to si maa n yọ s’oun loju oorun lo fi kan an. Awa ko gba ohun to sọ naa gbọ, oun paapaa si ti n kabaamọ fun ohun to ṣe yii pẹlu bo ṣe ti n sọrọ pẹlu wa lahaamọ to wa.

‘‘O ni ọmọri odo loun fi fọ ọ lori lati oju oorun lẹyin toun ṣaaju rẹ ji saye’’.

Alukoro ni gbara tawọn ba ti pari iwadii tawọn n ṣe lori rẹ lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ  ko le lọọ jiya ẹṣẹ rẹ lẹkun-unrẹrẹ.

 

Leave a Reply