Ọmọ Wasiu Ayinde di Oludamọran pataki si Gomina Sanwo-Olu

Monisọla Saka

Inu idunnu ati ayọ ni gbajumọ agba olorin Fuji ilẹ wa, King Wasiu Ayinde Marshall, tawọn eeyan mọ si K1 de Ultimate, wa bayii pẹlu bi ọmọ rẹ obinrin, Basirat Damilọla Marshal, ṣe di ọkan ninu awọn igbimọ ijọba ipinlẹ Eko.

Nibi fidio ayẹyẹ iwuye ati ọjọọbi Ọba Odi-Olowo, Sikirullah Apena, nijọba ibilẹ Odi-Olowo/Ojuwoye, nipinlẹ Eko, ti Wasiu Ayinde ti waa ṣere l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo ti fẹmi imoore han si Gomina Babajide Sanwo-Olu nita gbangba.

Wasiu to dupẹ lọwọ Sanwo-Olu nitori bo ṣe yan ọmọ ẹ to jẹ agbẹjọro to dantọ yii gẹgẹ bii Oludamọran pataki si gomina lori irinajo ati eto afẹ nipinlẹ Eko, sọ pe iṣẹ ti ọmọ oun ran oun ni lati dupẹ lọwọ Sanwo-Olu nita gbangba, oun si ti ṣe bẹẹ.

Bakan naa ni Damilọla funra ẹ, to dipo giga mu nileeṣẹ imọ ofin ara ẹ, iyẹn Damilọla Ayinde Marshal and Co., gba ori ẹrọ ayelujara lọ lati kede ipo tuntun ti wọn yan an si yii.

Nigba tawọn kan lori ayelujara n ṣaroye pe ipo rẹ lọwọ kan oṣelu ninu, ati pe nitori bi baba rẹ lẹnu ninu oṣelu ipinlẹ Eko ni wọn ṣe fi ipo naa da a lọla, iṣẹ ikini ku oriire ni pupọ eeyan ran si i.

Wọn ni o kaju ipo ti wọn fun un ni Gomina ṣe yan an, ati pe onikaluku lo n gbadua pe koun jọla awọn obi oun.

Tẹ o ba gbagbe, Damilọla yii kan naa lo bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn n ṣe iwọde EndSars lọjọsi, to ni awọn ọdọ naa di gbogbo ọna, wọn ko jẹ ki oun raaye kọja nitori iwọde ti ko nitumọ ti wọn n ṣe. Ọrọ yii lo bi awọn kan ninu ti wọn fi sọko ọrọ si i, toun naa si n fun wọn lesi. Ṣugbọn nigba ti eebu ati epe tawọn eeyan n gbe e ṣẹ pọ lo ti ori ikanni Instagraamu rẹ pa, o sọ ọ di eyi ti awọn eeyan ko le kọ ọrọ ranṣẹ sibẹ mọ, afẹni to ba fun ni aaye lati ṣe bẹẹ.

Leave a Reply