Ọmọ ‘Yahoo’ mejidinlogun ko sọwọ EFCC ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu

O kere tan, awọn ọmọ ‘Yahoo’ mejidinlogun ni wọn ti n ṣẹju peu lakolo ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, EFCC, ẹka tipinlẹ Kwara, fẹsun pe wọn n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

L’Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa, Adelẹyẹ Ayọdeji, Muhammed Ayub, Ọdẹlade Samuel, Sodiq Olanrewaju, Ọla Francis, Adeniyi Damilare, Ọlalekan Samad, Tunde Ayọdele, Zubair Buhari ati Ọladosu Naheem, nibi ti wọn fara pamọ si lagbegbe Sobi, Akerebiata, ati agbegbe Asadam, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Awọn miiran ni Olowokere Jamiu, Lawal Usman, Jamiu Abdulrasaq, Lawal Ahmed, Ọpẹyẹmi Samuel, Alarape Ahmed, Kolawole Daniel and Ganiyu Taofeek. Ọpọ awọn afurasi ọhun ni wọn jẹ akẹkọọ lawọn ileewe giga, agbabọọlu, ransọ-ransọ, awọn to n fọ aṣọ, awọn to n ta tẹtẹ lori ayelujara ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ajọ naa si ri awọn eroja bii ọkọ ayọkẹlẹ marun-un, foonu tuntun mejilelọgbọn, ẹrọ agbeletan mẹjọ ati bẹẹ bẹẹ lọ gba lọwọ wọn.

Leave a Reply