Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un yii, ni ile-ẹjọ giga kan to filu Ilọrin ṣebujokoo ti ni ki awọn ọkunrin mẹrin kan, Dauda Sọliu Tunde, Lambẹ Taiye, Ọmọgbọlahan Ibrahim Wasiu ati Ọlọrunfẹmi Ayọbami, lọọ fi ẹwọn oṣu mẹfa-mẹfa jura lori ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ti wọn fi kan wọn.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, lo wọ awọn afurasi naa lọ si kootu lori oniruuru ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn.
Sẹsan Ọla ati Mukhtar ti wọn ṣoju EFCC nile-ẹjọ ni wọn ko awọn ẹri maa jẹ mi niṣo siwaju adajọ.
Awọn afurasi naa gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan awọn. Lara awọn dukia ti wọn ba lọwọ wọn ni: ọkọ ayọkẹlẹ Lexus ES 350 kan, Toyota Camry kan, Hyundai Sonata kan, awọn laptop, ọpọ iPhone ati owo bamu lakaunti wọn.
Adajọ Mahmoud Abdulgafar, paṣẹ ki awọn ọdaran mẹrẹẹrin lọọ faṣọ penpe roko ọba fun oṣu mẹfa-mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Mandala, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
O fi kun un pe ki gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ wọn ati owo di ti ijọba apapọ