Monisọla Saka
Victoria Effiong, obinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan ti dero ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko, to wa lagbegbe Iba, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, nitori to kọ lati fẹ ọkunrin kan lẹyin to gbowo to din diẹ ni miliọnu mẹta Naira lọwọ rẹ.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ, to da lori yiyẹ adehun, fifi ọbẹ ẹyin jẹ ni niṣu ati fifi ọgbọn lu eeyan ni jibiti, ni wọn fi kan obinrin to n ṣiṣẹ telọ naa.
Agbefọba ni kootu ọhun, Insipẹkitọ Chinedu Njoku, ṣalaye fun kootu pe ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye ni Opopona Ajanaku, Isashi, nipinlẹ Eko.
“Niṣe ni Effiong fi ọgbọn lu Ọgbẹni Dominic Asuquo, ti i ṣe olupẹjọ ni gbaju-ẹ, pẹlu bo ṣe gba owo to din diẹ ni miliọnu mẹta Naira (2,866,000), lọwọ rẹ, to si ṣadehun fun un pe oun yoo fẹ ẹ, amọ to ja ọkunrin naa si ọlọpọn”.
Njoku ni lasiko ti olujẹjọ ṣi n fẹ Asuquo, onitọhun ra foonu olowo nla igbalode Iphone oni ẹgbẹrun lọna igba ati ogoji Naira (240,000) fun un, oriṣiriṣii aṣọ, bata, aago ọwọ ati baagi agbekọpa, ti gbogbo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira ataabọ, (350,000) fun un.
Bakan naa lo tun sọ pe Asuquo fun olujẹjọ lowo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (810,000), to si tun n fun un ni ẹgbẹrun mẹrin owo ounjẹ ojoojumọ foṣu meje, ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin ati aadọrin Naira din meji (868,000).
Ọmọbinrin yii tun gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira jade ninu akaunti Asuquo lati fi ra nnkan.
Ọrọ yii ni wọn lo di fọpomọyọ, nigba ti Asuquo ri i pe Effiong n palẹmọ lati ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mi-in, lai wo ti pe o ti lọọ fi Asuquo han awọn obi ẹ, tawọn funra wọn si mọ ajọṣepọ to wa laarin awọn mejeeji.
Amọ alaye Effiong ta ko ti ọkunrin olupẹjọ naa. Obinrin yii ṣalaye pe ko si ọrọ ifẹ kankan laarin awọn, nitori Asuquo mọ pe oun n fẹ ẹnikan tẹlẹ.
O ni loootọ loun gba foonu olowo nla lọwọ ẹ, foonu kekere oni ẹgbẹrun lọna ogun Naira atawọn nnkan mi-in, ṣugbọn gbogbo b’oun ṣe sọ fun Asuquo lati ma fowo ranṣẹ s’oun mọ ni ko gbọ, nitori ko ba oun lara mu.
Bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ bẹbẹ niwaju adajọ Majisireeti naa, Arabinrin O. M. Ogun, pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn ka si oun lọrun, agbefọba ni ẹṣẹ to ni ijiya ninu ninu iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015 ni.
Adajọ fun un ni beeli ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000), pẹlu oniduuro meji, ti ẹni kọọkan wọn gbọdọ san ẹgbẹrun lọna igba Naira bakan naa.
Bẹẹ ni asajọ paṣẹ pe ọkan ninu awọn ti wọn ba duro fun olujẹjọ gbọdọ jẹ ẹbi rẹ gangan. Ati pe iru ẹni bẹẹ gbọdọ fi ẹri owo-ori to n san fun ijọba ipinlẹ Eko han.
Adajọ sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.