Bi ẹ ti n wo ọmọbinrin daadaa yii, ko si laye mọ. Ọgbọnjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, lo gba ẹmi ara ẹ nipa pipokunso sori igi mangoro laduugbo wọn, nitori irọ ti wọn pa mọ ọn pe o ji pata mẹta lo ṣe gbe igbesẹ iku naa.
Orukọ ọmọdebinrin naa ni Agnes Kayombo, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni. Agbegbe kan ti wọn n pe ni Mwinilunga, lorilẹ-ede Zambia, loun ati iya rẹ, Lucy Kayombo, n gbe. Iya rẹ yii naa la gbọ pe o ra pata tuntun mẹta l’Ọjọruu ọsẹ to kọja lọhun-un, o si ko o sinu apoti aṣọ kan lọtọ, lo ba gbagbe rẹ sibẹ.
Nigba ti Iya Agnes fẹẹ wọ ninu awọn pata naa lọjọ Satide ti wahala ṣẹlẹ yii, o wa awọn pata ọhun titi ko ri wọn, ko si ranti ibi to ko wọn si mọ, n lo ba bẹrẹ si i tu gbogbo ile kiri.
Bi iya naa ṣe tule to, ko ri awọn pata tuntun naa, bẹẹ ni ọkan rẹ ko lọ sibi apoti to ko o si mọ, n lo ba beere lọwọ Agnes pe ṣe o ba oun ri awọn pata naa, iyẹn loun ko ri pata kankan.
Esi ti ọmọ yii fun iya rẹ ko tẹ iya lọrun, wọn ni niṣe niya bẹrẹ si i sọ pe Agnes ti ko awọn pata naa pamọ, nigba to jẹ saisi kan naa lawọn jọ n lo, o ti ji wọn pamọ, ko fẹẹ jẹwọ ni. Lẹyin to bu u titi, tiyẹn ko yee sọ pe oun ko ji pata, iya rẹ tun yọ ẹgba si i, o lu u daadaa, ṣugbọn niṣe lọmọbinrin yii kan n sunkun kikoro, ko si yee sọ pe oun ko ji pata.
Aṣe ohun ti iya rẹ sọ yii ti dun un kọja ibi to yẹ, idunrun ole mọ naa ko gba ibi ire lara Agnes pẹlu lilu to tun un lu u. Bo ṣe di lalẹ, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Satide ọhun, Agnes yọ jade nile, o si lọọ pokunso sara igi mangoro kan laduugbo wọn.
Nigba tawọn eeyan yoo fi ri i, ẹlẹmi ti gba a.