Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Nasaru, nijọba, ibilẹ Ningi, nipinlẹ Bauchi, ti sọ pe ọdọ awọn ni Danladi Ibrahim, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan wa, to si n ran awọn lọwọ nipa ohun to ri to fi foogun oorun sinu ohun mimu ọmọdebinrin ti ko ju ọdun mẹwaa lọ yii, ti ọmọ naa si sun lọ fọnfọn, lẹyin naa lo fipa jabaale rẹ.
ALAROYE gbọ pe, lagbegbe Nasaru, nijọba ibilẹ Ningi yii kan naa ni Danladi n gbe pẹlu awọn obi ọmọ yii, ṣugbọn ti ko mọ ọna to le gbe e gba lati fipa ba a lo pọ afigba to da ọgbọn buruku kan bayii. Lasiko tawọn obi ọmọ yii ko si nile lo foogun oorun sinu ohun mimu ẹlẹridodo fun ọmo naa, to si lo anfaani ọhun lati ba a sun nigba ti oorun n kun ọmọ ọhun gidigidi.
Ohun ta a gbọ ni pe ni gbogbo akoko ti Danladi n fipa jabaale ọmọ yii, ọmọ ọhun ko le sọrọ soke rara, nitori pe oogun oorun to fi sinu ohun mimu ọhun pọ gan-an ni.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, S.P Ahmed Mohammed Wakil, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lakooko to n ṣafihan Danladi sọ pe baba ọmọ ọhun lo waa fọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa teṣan Ningi leti, tawọn si tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu Danladi nile rẹ. Loju-ẹsẹ naa la si ti gbe Nadiya ti Danladi fipa ba sun lọ si ọsibitu ijọba kan fun itọju to peye, nitori pe ṣe lẹjẹ n jade loju ara ọmọ naa, to si da bii ẹni pe Danladi ti ba oju ara ọmọ ọhun jẹ kọja afẹnusọ bayii.
Alukoro ni, ‘Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni Ọgbẹni Abubarkar Garba ti i ṣe Baba Nadiya waa fọrọ iṣẹlẹ ohun to awọn ọlọpaa teṣan Ningi leti, ta a si tẹle e lọ sile rẹ. Lẹyin ta a ṣẹwadii tan la too fọwọ ofin mu Danladi, nitori pe o jẹbi ẹsun iwa ọdaran ti baba ọmọ naa fi kan an, to si ti jẹwọ lọdọ wa pe loootọ loun foogun oorun sinu ohun mimu ọmọdebinrin naa ko too di pe oun ba a sun. Oriṣii ọsibitu mẹta ọtọọtọ la ti gbe ọmọ ọhun de bayii. Ọsibitu ijọba kan to wa lagbegbe Ningi, la kọkọ gbe ọmọ ọhun lọ, ṣugbọn ti wọn ko gba a lọwọ wa rara, wọn ni ka maa gbe e lọ si ọsibitu kan ti wọn n pe ni ‘ National Obstetrics Fistula Centre’ (NOFIC) to wa nijọba ibilẹ Ningi ṣugbọn tawon yẹn naa tun sọ pe, ka maa gbe ọmọ ọhun lọ si ọsibitu mi-in nitori pe oju ara ọmọ ọhun ti bajẹ kọja afẹnusọ, ti ẹjẹ si n da jade nibẹ gidi. Ọsibitu ‘Federal Medical Centre’ (FMC), kan to wa niluu Birnin Kudu, nipinlẹ Jigawa, la pada gbe ọmo ọhun lọ bayii, tawọn dokita si ti n ṣetọju rẹ lọwọ.
Alukoro ọhun ni ọlọpaa ko ni i dunu si ẹni ti ofin ba gba mu pe o hu iwa ọdaran nipinlẹ naa, paapaa ju lọ, nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa ti sọ pe kawọn ma gba gbẹrẹ rara fawọn ọdaran gbogbo ti wọn fẹẹ sọ ipinlẹ Bauchi di ile gbigbe wọn.
Bakan naa lo sọ pe gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan nipa Danladi, lawọn yoo ti foju rẹ bale-ẹjọ, ko le lọọ fimu kata ofin.