Ọlawale Ajao, Ibadan
“Oni nigbẹyin aye mi. Lonii yii gan-an ni mo ri ile aye mọ, nitori mo n lọọ ba Ẹlẹdaa mi lonii”.
Eyi lọrọ idagbere ti ọkunrin oniṣowo kan, Ọgbẹni Onoh Chukwuma Richard kọ si ikanni ibanidọrẹẹ (fesibuuku) rẹ fun ẹbi, ara, ọrẹ, atawọn ololufẹ ẹ ko too di po gbẹmi ara ẹ.
Ọpọ awọn to ka atẹranṣẹ ọhun ni ko ka a si nnkan babara, wọn ro pe ara awọn oriṣiiriṣii ẹ̀fẹ̀ ati ẹ̀tàn tawọn eeyan maa n gbe sori ẹrọ ayelujara lasan ni.
Ṣugbọn awọn to sun mọ Ọgbẹni Richard daadaa mọ pe ọkunrin naa kí i ṣe onikebekebe eeyan bẹẹ. Nitori naa, wọn sare lọ sile lọọ wo o, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi dele, ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun ni ọmọkunrin naa wa, koda, o ti n pọkaka iku, nitori majele to rọ mu. Ni wọn ba sare gbe e lọ si ọsibitu boya awọn dokita yoo le ri ẹmi rẹ da pada saye. Wọn sare gbe e lọ sileewosan ijọ Kirisitẹni kan to wa niluu Unahia, lati gbẹmi ẹ la. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe pẹlu gbogbo itọju ti wọn fun un, akukọ pada kọ lẹyin ọmọkunrin.
Majele lọkunrin ti ko le ju ẹni ọgbọn (30) ọdun lọ yii gbe jẹ ,nitori wọn ba ike oogun aṣekupani ti wọn n pe ni sniper nni ninu ile ẹ nibẹ.
Eyi lo jẹ ki ara fu awọn eeyan naa pe jagunlabi ti gbe majele naa mu tan ko too kọ ọrọ idagbere to kọ sori ẹrọ ayelujara naa.
Ninu ọrọ idagbere ọhun lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan kan to ti kopa pataki ninu aye ẹ nigba to wa lode aye.
Gẹgẹ bo ṣe kọ ọ, “Oni nigbẹyin aye mi. Lonii yii gan-an ni mo ri ile aye mọ nitori mo n lọọ ba Ẹlẹdaa mi lonii. Mo dupẹ lọwọ Ọgbẹni Chima Anyaso, Ikukuoma Abia, Kelvin Jombo Onumah, Ekwueme Ohafia, ati ẹyin ọrẹ mi gbogbo. Ẹmi mi wa pẹlu gbogbo yin”.
ALAROYE gbọ pe niṣe l’Ọgbẹni Richard fowo ta tẹtẹ, ṣugbọn to ja si pe o fowo ṣofo, nitori nnkan ko ṣẹnuure fun un pẹlu bi ko ṣe jẹ nidii tẹtẹ to ta naa.
Gẹgẹ bi ẹnikan to n jẹ Obika James Abuchi, ṣe fun un lesi ninu ọrọ idagbere to kọ si Fesibuuku, onitọhun fidi ẹ mulẹ, o ni, “Ṣebi itiju ẹ̀sín ati ẹlẹ́yà ti awọn to o jẹ ni gbese maa fi ẹ ṣe lo sa fun to o fi pa ara rẹ danu.
“Nigba ti iwọ (Richard) naa ni miliọnu kan Naira lọwọ, to o tun ya miliọnu kan aabọ Naira (₦1.5m) kun un, to o waa lọọ fi aduru owo yẹn ta tẹtẹ. Ta lo kọ ẹ niru eyi, Onoh”?
Ọmọ bibi ilu Ututu, nijọba ibilẹ Arochukwu, nipinlẹ Abia, ni wọn pe Ọgbẹni Richard to gbẹmi ara ẹ yii, wọn loun ni alukoro ẹgbẹ idagbasoke ilu Ututu, ti i ṣe ilu abinibi ẹ ko too ku.