Faith Adebọla
Akẹkọọ ẹni ogun ọdun kan ti wọn lo ṣẹṣẹ ṣedanwo iwe-mẹwaa tan, Mohammed Yusuf, ti wa lakolo ọlọpaa latari bi wọn ṣe lo mu egboogi oloro yo. Igbo lo mu, igba ti kinni naa ko si i lori tan, ko ṣe meni ṣe meji, niṣe lo ki baba ẹ to ti darugbo mọlẹ, Alaaji Ibrahim Yusuf, lo ba da ẹṣẹ bo o, o tun la nnkan mọ ọn lori titi to fi dakẹ mọ ọn lọwọ.
Iṣẹlẹ yii waye lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, nile kan to wa lẹyin ọgba ileewe Saint Mary Primary School, to wa lọna Lọkọja si Ankpa, niluu Lọkọja, nipinlẹ Kogi.
Ba a ṣe gbọ latọdọ Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), wọn ni inu ọgbara ẹjẹ ni wọn ba baba arugbo tọjọ ori ẹ din diẹ ni ọgọrin ọdun yii. Nigba tawọn aladuugbo ṣakiyesi pe nnkan aburu kan n ṣẹlẹ nile naa ni wọn sare lọ sibẹ, wọn si gbe baba yii digbadigba de’le iwosan kan to wa nitosi, ṣugbọn awọn dokita ko ri ẹmi ẹ du rara, wọn lo ti dakẹ.
Ọkunrin kan, Bello Nana, sọ pe iṣẹlẹ ọhun ṣoju oun, o ṣalaye fawọn oniroyin pe ‘alaamulegbe wọn ni mi, ile wa fẹgbẹ kan ara wọn ni. Lataarọ la ti n ṣakiyesi bọmọkunrin yii ṣe n ṣe wanranwanran kiri adugbo, mo sọ fun baba ẹ pe ko jẹ ka lọọ fọlọpaa mu un, tabi ka lọọ fẹjọ ẹ sun ni bareke ṣọja ki wọn le waa mu un.
Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ lemi lọ sibi iṣẹ, aago mejila lo yẹ ki n ṣiwọ, ṣugbọn aago mẹwaa ni mo ṣiwọ lọjọ naa, bi mo ṣe de ẹnu geeti, mo gbalẹkun titi, mo pariwo, ṣugbọn mi o rẹni da mi lohun, mo ṣaa dọgbọn ṣilẹkun pẹlu kọkọrọ mi latinu, mo de ẹnu ilẹkun, mo ṣakiyesi pe ọmọkunrin naa wa nile, mo si bi i leere pe baba n kọ, o ni baba o si nile. Mo ni nibo ni baba lọ, tori mo mọ pe baba ki i jade taago mẹfa alẹ ba ti lu, wọn maa tilẹkun mọri ni, wọn o si ki i jẹ kọmọkunrin yii wa lọdọ awọn, tori naa, o ya mi lẹnu bo ṣe jẹ inu yara baba lọmọ naa ti n da mi lohun, ara fu mi, ni mo ba pe afẹsọna mi lori foonu pe ko sare wa o, nnkan kan ti ṣẹlẹ, a tun pe aago baba naa, ṣugbọn ko gbe e.
A pe awọn ọlọpaa lori aago, bi wọn ṣe de ni wọn wọle, wọn ba baba ninu agbara ẹjẹ, wọn ba ọmọ ẹ to lu u pa naa to n ṣẹju pako, a ba aloku ati amuku egboogi oloro to mu lẹgbẹẹ kan nibẹ, a sare boya a ṣi le du ẹmi baba, ṣugbọn ẹpa o boro mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, DSP William Ovye Aya, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loootọ lawọn gba ipe pajawiri lori iṣẹlẹ ọhun lalẹ Ọjọruu, awọn si sare debẹ, wọn ya fọto ohun ti wọn ba. O ni afurasi ọdaran naa ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii siwaju si i, awọn si ti gbe oku Ibrahim si mọṣuari fun ayẹwo iṣegun.