Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Boga, nipinlẹ Adamawa, ti mu Ọgbẹni Sadiq Idrissu, ẹni ọgbọn ọdun, to pa iya rẹ lẹyin to fẹsun kan an pe ajẹ ni, ati pe igba gbogbo lo maa n yọ soun loju oorun oun, ti aya oun si maa n ja toun ba ti foju kan an loju ala oun.
ALAROYE gbọ pe ọjọ karun-un, oṣu Kejila, ọdun yii, ni Sadiq yinbọn pa mama rẹ lẹyin to ti ki i nilọ laimọye igba pe ko jawọ ninu ẹgbẹ ajẹ to wa, ati pe ija baba rẹ wa lara ohun ti Sadiq loun n gbe toun fi pa mama oun yii. O ni aanu baba oun n ṣe oun bo ti ṣe n ba iya oun to jẹ ajẹ gbele fun aimọye ọdun sẹyin bayii.
Loju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa agbegbe Boga, nijọba ibilẹ Gombi, ti fọwọ ofin gba a mu loun paapaa ti sọ pe ki wọn ma laagun jinna rara, o ni inu iya oun yii lo n bi oun toun ṣe pa a danu.
Ṣa o, awọn aradugbo kan ti wọn mọ iru egboogi oloro ‘Suck ati Die’ ti ọmọ ọhun maa n mu nigba gbogbo sọ pe, o ṣee ṣe ko jẹ pe egboogi oloro ọhun lo ko si i lori to fi ṣiwa-hu, to fi di pe o yinbọn pa iya rẹ danu.
Ọdọ awọn ọlọpaa ọhun ni Sadia ti jẹwọ pe,’’Emi nikan kọ lo mọ pe ajẹ ni oloogbe naa, awọn kọọkan laduugbo wa mọ pe ogbologboo ajẹ niyaa mi yii, wọn tiẹ ti n bu mi laduugbo. Ju gbogbo rẹ lọ, aanu baba mi lo n ṣe mi gidi pẹlu bo ṣe ti n ba iya mi gbele lati ọjọ yii wa, ko kuku mọ pe iyawo rẹ wa lara awọn ẹni to n fa ọwọ aago rẹ sẹyin. Lọjọ ti ma a gbẹmi rẹ, ṣe ni mo yọ kẹlẹkẹlẹ lọ sile baba mi, mo ri aburo mi kan to n sun lọwọ, mi o ji i silẹ rara, bẹẹ ni mo lọọ wo iya mi nibi to maa n sun si, mi o ba a lori bẹẹdi rẹ, mo si pa ọkan pọ pe o ni lati jẹ pe o ti lọ sinu ipade ẹgbẹ ajẹ rẹ ni mi o ṣe ba a nile lasiko ti mo wa sile naa. Bi mo ṣe fẹẹ jade bayii ni mo pade rẹ lẹnu ọna ile wa, mi o ro o lẹẹmeji rara, ṣe ni mo doju ibọn ṣakabula kan to wa lọwọ mi kọ ọ, ti mo si yin in lu u gbau. Loju-ẹsẹ lo ṣubu lulẹ, to si ku patapata. Ki n too pa mama mi yii lo jẹ pe ṣe lo maa n yọ si mi loju ala nigba gbogbo, ọpọ igba lo si maa n dẹru ba mi loju oorun mi. Ẹru naa pọ debii pe ki i wu mi lati lọọ sun ni alẹ mọ rara, nitori pe mi o mọ ohun ti ma a tun ba pade loju oorun mi’’.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Nguroje, loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, CP Afọlabi Babatọla, paapaa ti gbọ si i, to si ti paṣẹ pe ki wọn taari ọdaran ọhun lọ sọdọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to n ri sọrọ iwa ọdaran laarin ilu, ki wọn le ṣewadii daadaa nipa ọrọ rẹ, ko too di pe wọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ lori ohun to ṣe.