Ọmọọdun mẹtala tiyawo ẹ bi ni Taofeek n fipa ba lo pọ l’Owode

Gbenga Amos, Ogun

Ọwọ ṣikun ofin ti tẹ baale ile ẹni ogoji ọdun kan, Taofeek Sulaiman, niluu Owode, nijọba ibilẹ Guusu Yewa, nipinlẹ Ogun. Niṣe lọkunrin yii n fipa ba ọmọ tiyawo ẹ gbe waa fẹ ẹ ti ko ju ọmọọdun mẹtala pere lọ laṣepọ. Bo ṣe n ku iya ọmọ naa mọlẹ, lo n yata lori ẹgbẹ ọmọ bibi ẹ.

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe f’ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, o ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, lọwọ awọn agbofinro tẹ afurasi ọdaran naa.

O ni iyawo baba yii, to jẹ iya ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun lo mẹjọ ọkọ rẹ wa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Owode Yewa, o ni kawọn ọlọpaa gbọ eemọ toun kan lọọdẹ ọkọ o, niṣe lọkọ toun ṣẹṣẹ fẹ lẹyin tọkọ oun ku n ba ọmọ oun sun.

Wọn beere lọwọ ẹ pe bawo lo ṣe mọ, ati pe igba wo niṣẹlẹ naa waye, o si ṣalaye fun wọn pe ọmọ oun lo taṣiiri naa foun, o loun ṣakiyesi pe iṣesi ọmọ naa yatọ, o jọ pe nnkan kan jẹ ẹdun ọkan fun un, loun ba tẹ ẹ ninu. Ibẹ lọmọbinrin yii ti jẹwọ pe lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa yii, ni baba buruku toun n pe lọkọ oun tuntun yii ti n gun ọmọbinrin naa bii ẹṣin.

O lọmọ naa sọ pe Taofeek ti kilọ foun lati ma ṣe jẹ ki ẹda alaaye kankan gbọ nipa ọrọ yii, afi toun ba fẹẹ tọ iku wo lo ku.

Eyi lo mu ki DPO teṣan Owode Yewa, CSP Bala Muhammed, paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati lọọ mu baale ile naa wa, wọn si ri i mu.

Ni teṣan, wọn lọkunrin naa ko tiẹ la awọn ọlọpaa loogun rara to fi jẹwọ, o ni ki wọn ṣaanu oun, iṣẹ Eṣu ni, oun o tiẹ mọ ohun toun iba pe e, oun o m’ohun to gbe oun dedii iwa palapala bẹẹ.

Wọn tun bi i pe o ti togba meloo tiṣẹlẹ naa ti waye, o loun o tiẹ le sọ, ṣugbọn o ti ju ẹẹkan tabi eemeji lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari Taofeek afẹmọ-fẹyaa sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n gbogun ti hihuwa aidaa sawọn ọmọde, ati ifiniṣowo ẹru lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta.

O ni ki wọn tubọ ṣewadii to lọọrin nipa iṣẹlẹ yii, ki afurasi naa le fara han niwaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply