Adewale Adeoye
Ọsẹ yii gan-an ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa lawọn maa foju Ọgbẹni Ya Zakari, dẹrẹba mọto ayọkẹlẹ kan to fi mọto rẹ pa awọn ọmọ iya mẹta lasiko to mu ọti amupara yo tan lọsẹ to kọja yii. Orukọ awọn ọmọ ọhun ni Nusaiba, Maryam ati Rumaisa.
Afi bii pe wọn ran an sawọn ọmọ ọhun ni, nitori pe bi awọn ọmọ naa ṣe n du u pe ko ma fi mọto rẹ kọ lu awọn, bẹẹ lo n le wọn ka, afigba to gbẹmi wọn loju rẹ too la.
Ọjọ Ẹti Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn ọmọ ọhun lọọ ki iyawo ẹgbọn wọn kan laduugbo Rafin-Kunama, lojuna marosẹ Abaji, niluu kekere kan ti wọn n pe ni Toto, nipinle Nasarawa. Lasiko ti wọn n dari bọ ni wọn pade iku ojiji naa. Ẹgbẹ titi lawọn ọmọ naa n gba lọjọ naa gẹgẹ bii iṣe wọn nigba gbogbo, ṣugbọn nitori pe Ya Zakari to n wa ọkọ ọhun ti mu ọti amupara yo lo ṣe lọọ ya pa wọn.
Ọgbẹni Suleiman Ozakwo ti i ṣe baba awọn ọmọ naa to jẹ olukọ agba nileewe alakọọbẹrẹ kan ti wọn n pe ni, ‘Anguwar Baiyi’, nijọba ibilẹ Toto, nipinlẹ Nasarawa, to ba awọn oniroyin kan sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe ibanujẹ nla gbaa niku awọn ọmọ naa jẹ f’oun, ṣugbọn oun fa gbogbo rẹ le Ọlọrun Ọba Allah atawọn ọlọpaa lọwọ.
O ni, ‘Ki i ṣe igba akọkọ ree tawọn ọmọ naa maa lọ sile iyawo ẹgbọn wọn, igba gbogbo ni wọn maa n lọ, ṣugbọn nitori pe Ya Zakari to jẹ dẹrẹba mọto ayọkẹlẹ naa ti mu ọti amupara lo ṣe lọọ ya pa wọn lasiko ti wọn n bọ wa sile.
O waa rawọ ẹbẹ sawọn araalu ọhun pe ki wọn maa ranti awọn ọmọ naa ninu adura wọn nigba gbogbo.
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti pari iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ohun to ku bayii ni lati foju Ya Zakari to pa awọn ọmọ iya mẹta lẹẹkan naa bale-ẹjọ.