Ọna kan pataki lati da ogo ati ọrọ-aje orile-ede Naijiria pada ni ki ẹ dibo fun mi-Tinubu

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pe ki wọn ma jẹ ki awọn oloṣelu ẹlẹtan tan wọn jẹ pẹlu irọ ati ileri ti ko ni i wa si imuṣẹ. O ni ki wọn dibo fun ẹgbẹ Onigbaalẹ ninu eto idibo ọdun 2024. O ṣalaye pe ọna kan pataki lati le da ogo ati ọrọ aje orile-ede Naijiria pada ni ki wọn dibo fun oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC yooku.

Tinubu sọrọ yii niluu Ado-Ekiti, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lasiko ti wọn n ṣe ibura wọle fun Gomina tuntun nipinlẹ naa, Biọdun Oyebanji ati Igbakeji rẹ, Arabinrin Monisọla Afuyẹ.

O kilọ fawọn eeyan ipinlẹ Ekiti pe ki wọn la oju wọn daadaa, ki wọn ma ṣe jẹ ki awọn oloṣelu kan ti wọn ko ni ohun kan tabi omiiran lati ṣe fun itẹsiwaju ipinlẹ wọn tan wọn jẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ “Awọn kan maa wa ti wọn yoo pe orukọ wọn ni Atiku, bakan naa ni awọn miiran yoo tun wa ti wọn yoo sọ pe orukọ awọn n jẹ Peter Obi, ẹ jọwọ, ẹ ma da wọn loun, ti wọn ba ti wa, kia ni ki ẹ sọ fun wọn pe ẹni kan tiẹ mọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu, ati ẹni kan ti ẹ fẹẹ dibo fun ni Bọla Tinubu.

“Ẹ ma jẹ ki wọn tan yin jẹ tabi ki wọn yi ero ọkan yin pada, awọn miiran yoo wa lati tọrọ ibo yin, ẹ sọ fun wọn pe ẹgbẹ Onigbaalẹ nikan ni ẹgbẹ ti ẹ mọ l’Ekiti. ”

Nigba to n sọrọ nipa gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe ọpa aṣẹ fun nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji, oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ naa sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pe ki wọn gbaruku ti ko le ṣe aṣeyọri ninu ijọba rẹ.

O juwe gomina tuntun naa gẹgẹ bii oloṣelu pataki ti ko dojuti awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti wọn dibo fun.

O fi asiko ayẹyẹ naa tọrọ ibo lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti, o ni ti wọn ba dibo fun oun, gbogbo ogo ipinlẹ naa ti awọn oloṣelu igba kan ti ko lọ ni oun yoo da pada.

 

Leave a Reply