Monisọla Saka
Ẹgbẹ kan lapa Ariwa orilẹ-ede yii, Concerned Northern Forum, ti lawọn o fara mọ igbesẹ ti banki apapọ ilẹ wa fẹẹ gbe lori atuntẹ awọn owo Naira tuntun, bẹrẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun to n bọ yii.
Gẹgẹ bi olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, ṣe sọ, L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, o ni lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni banki naa yoo maa ko awọn owo tuntun naa sita faraalu, kawọn eeyan si bẹrẹ si i maa na eyi to wa nilẹ tẹlẹ sita nitori inu oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ yii, lawọn yoo ko gbogbo rẹ kuro nilẹ.
Awọn ẹgbẹ yii ni obitibiti owo, agaga, owo awọn eeyan to sanwo-ori ni wọn yoo tun na le atuntẹ owo naa.
Lasiko ti ẹgbẹ ọhun n sọrọ lodi si ohun ti banki apapọ, CBN, sọ lati ẹnu agbẹnusọ wọn, Abdulsalam Kazeem, l’Ọjọruu, Wẹsidee, niluu Kaduna, ni wọn ti sọ pe, atuntẹ owo Naira ko ni iyi kankan to fẹẹ bu kun owo Naijiria, iyẹn o dẹ sọ pe ko gbe pẹẹli bii owo awọn orileede yooku, o ni eleyii ko tun tumọ si pe atuntẹ owo yii yoo mu aye rọgbọ fun awọn eeyan ilẹ yii si i, nitori eyi si lawọn ko ṣe le fara mọ ọn.
O ni, “Ọrọ ipade apero ti olori banki apapọ ilẹ wa pe niluu Abuja, nibi to ti sọ pe awọn fẹẹ ṣe atuntẹ awọn owo ilẹ wa kan bii igba Naira (200), ẹẹdẹgbẹta Naira(500) ati ẹgbẹrun kan(1000) Naira, lati inu oṣu Kejila, ọdun yii, ti de si etiigbọ ẹgbẹ wa. Si awa gẹgẹ bii ẹgbẹ, igbesẹ yii ko ja mọ nnkan kan. Eto ọrọ aje wa gẹgẹ bii orilẹ-ede ti dẹnu kọlẹ, owo wa si ti bajẹ kọja bo ṣe yẹ, banki apapọ ko waa ri ohunkohun kan ṣe si i, ohun ti wọn le ṣe gẹgẹ bii adari ko waa ju ki wọn pa awọ awọn owo wa da, ki wọn gbe ara ọtun yọ fun wa lọ.
“Owo rọgunrọgun tawọn eeyan n san gẹgẹ bii owo-ori ni yoo tun ba eleyii lọ. Ko tilẹ tun waa jẹ asiko ti nnkan dẹrun, niru akoko to jẹ pe a n ya owo lati fi ṣe awọn nnkan to jẹ koko ninu aba eto iṣuna ilẹ wa, bẹẹ la n ya awọn owo mi-in lati fi rọ gbese to wa nilẹ tẹlẹ san ni, ọna abayọ kan ṣoṣo ti banki to ga ju lọ nilẹ wa ri ko ju ki wọn dara si owo wa lara, ki wọn si gbe e jade lara ọtun lọ.
‘‘Ọrọ yii kan wa, o si n ka wa lara gẹgẹ bii aṣoju awọn eeyan ati agbegbe wa. Ṣe atunṣe yii fẹẹ yi igbe aye awọn eeyan pada si ti daadaa ni abi o fẹẹ mu ki owo tiwa naa niyi lagbaaye? ‘‘Gbogbo awọn ibeere to n tawọ tasẹ ninu wa ree, tẹ o ba waa ri idahun gidi kan fun wa gẹgẹ bi awa gan-an ko ṣe reti ikankan lati ọdọ yin, ki banki giga ọhun yaa pa ọrọ owo tuntun ni titẹ ti kiakia, bi bẹẹ kọ, awa atawọn ẹgbẹ mi-in lawujọ ti ọrọ ilu yii ba mumu laya wọn maa kọ ọ ninu ati nita agbegbe wa.
‘‘Ẹ ti ibi owo Naira kan si dọla tabi pansi (pounds) wo o, nibẹ lẹ oo ti ri i pe owo Naira ti bajẹ patapata, aba eto ọrọ aje to dara lo ku ta a nilo bayii lati mu ki owo wa le duro lẹgbẹẹ dọla ati pansi lagbaaye”.
Bakan naa lo lawọn nigbagbọ pe, owo ti wọn fẹẹ tun tẹ yii, ọna lati lati wa ijẹ fawọn eeyan kan tabi awọn agbaṣẹṣe ki saa eto ijọba yii too wa sopin ni. Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ileesẹ banki apapo wa kede pe awọn fẹẹ yi awọn to wa lara awọn owo ilẹ wa pada, ti onikaluku si n sọ ero rẹ lori eleyii.