Monisọla Saka
Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe agbẹnusọ aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti kilọ fawọn ẹya Igbo ti wọn n gbe nipinlẹ Eko, lati ma ṣe da sọrọ oṣelu mọ nipinlẹ naa.
Ọnanuga to jẹ adari eto iroyin fun ikọ onipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC, sọrọ yii lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ọrọ to sọ yii waye latari fa-n-fa ọrọ oṣelu to the n waye laarin awọn Yoruba atawọn Igbo ti wọn waa ṣe atipo nipinlẹ Eko, lẹyin ti esi idibo aarẹ to waye loṣu Keji, ọdun yii, ti fi han pe Peter Obi ti ẹgbẹ Labour Party, lo ni ibo to pọ ju lọ nipinlẹ Eko, to si gba Eko mọ Aṣiwaju Bọla Tinubu lọwọ ni fulenge fulenge awọn ọmọ Ibo ti bẹrẹ.
Eyi lo mu kawọn ti ki i ṣe ọmọ Eko tabi ẹya Yoruba, ṣugbọn ti wọn n gbe nipinlẹ naa, maa sọ pe ipinlẹ Eko ki i ṣe ilẹ ẹnikẹni, ọrọ yii si ti bi Ige, o ti bi Adubi, laarin awọn eeyan apa Ila Oorun Guusu orilẹ-ede yii, atawọn ọmọ Yoruba.
Ọnanuga ni, “Ẹ jẹ ki ọdun 2023 yii jẹ igba ikẹyin tẹ ẹ maa da sọrọ oṣelu nipinlẹ Eko. Ẹ ma ṣan aṣọ iru ẹ ṣoro to ba di ọdun 2027. Bii ipinlẹ Anambra, Imo, atawọn ipinlẹ mi-in lorilẹ-ede Naijiria ni Eko naa ri. Ki i ṣe ilu tẹnikan ko ni, ki i si i ṣe olu ilu orilẹ-ede yii. Ilẹ Yoruba ni, ẹ ṣọ ara yin”.
Lati bii ọjọ meloo kan si eto idibo gomina ati tawọn aṣofin ipinlẹ yii, ni họwuhọwu ti n bẹ silẹ nipinlẹ Eko, latari ọrọ ẹlẹyamẹya.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Oluṣẹgun Ọṣọba, rọ awọn ọmọ Ibo to wa l’Ekoo ṣaaju ọjọ idibo, lati ma ṣe sọ eto idibo di ti ẹlẹyamẹya. Ọrọ ẹlẹyamẹya yii ti waa gba ori ẹrọ ayelujara kan debii pe awọn Ibo n ba awọn to nilẹ fa a gidigidi ni. Ọrọ yii si ti ta ba gomina to wa lori aleefa nipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati oludije funpo gomina lẹgbẹ Labour Party, Gbadebọ Rhodes-Vivour, gẹgẹ bi wọn ṣe n fojoojumọ ta si wọn lori ayelujara.
Latigba ti ibo gomina ti ku bii ọsẹ kan, ni wọn ti lawọn kan n dunkooko mọ ẹnikẹni ti ko ba fi tawọn Yoruba ṣe lọjọ idibo. Oniruuru wahala ati ijangbọn lo si waye, kaakiri awọn ibudo idibo nipinlẹ Eko nitori ọrọ awọn Yoruba atawọn Ibo yii.