Adewale Adeoye
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Cross Rivers, Balarabe Sule, ti sọ pe ọdọ awọn ni Ọnarebu Patrick Uguge to ti figba kan jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa tẹlẹ wa bayii, to si n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn lori ẹsun fifipa ba ni sun ti wọn fi kan an. Wọn ni lẹsẹkẹsẹ tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn lawọn yoo gbe Ọnarebu yii lọ sile-ẹjọ fun idajọ to peye lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an.
Ọnarebu yii ni wọn fẹsun kan pe o fipa ba ọkan lara awọn aburo iyawo rẹ sun lotẹẹli kan ti wọn n pe ni Ogoja, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko ti omidan naa ti ọjọ ori rẹ ko ju mọkandinlogun lọ wa pẹlu rẹ ninu otẹẹli naa.
Patrick ti wọn fẹsun kan ọhun la gbọ pe o ṣoju agbegbe Ogoja, nileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa lọdun 2007 si 2015.
Agbẹjọro ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan nipinlẹ naa ‘ Human Right Council Initiative’ (BRCI) , James Ibor bu ẹnu atẹ lu bawọn agbaaya kọọkan ṣe n fipa ba awọn ọmọ keekeeke sun niluu naa bayii, eyi to sọ pe ki i ṣohun to daa rara, to si yẹ ki ijiya nla wa fun ẹni yoowu tọwọ ofin ba tẹ.
‘‘Omidan ti ọkunrin yii fipa ba lo pọ lo waa fẹjọ sun ajọ wa pe ọkunrin yii fipa ba oun sun daadaa ni otẹẹli kan to wa lagbegbe Ogoja. Loju-ẹsẹ la ti ṣewadii nipa ọrọ ọhun, ta a si fi eyi to jẹ ọọtọ nibẹ mulẹ. Lẹyin naa la ṣẹṣẹ too kọwe sileeṣẹ ọlọpaa lori ẹsun naa, tawọn agbofinro si tete lọọ fọwọ ofin mu ọkunrin yii pe ko waa sọ tẹnu rẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan an yii.
‘‘Ẹṣẹ nla gbaa ni ki wọn fipa baayan sun nilẹ Naijiria, ti ijiya nla si wa fun ẹni to ba ṣe bẹẹ. A gbọdọ daabo bo awọn obinrin lọwọ awọn ikooko ti wọn ko lojuti rara. Iwadii wa lọdọ awọn obi ọmọ naa fidi rẹ mule pe omidan naa ko ti i mọ ọkunrin ko too di pe Ọnarebu yii fipa ja ibale rẹ’’.