Oogun ara riro ni Jẹrimaya loun fẹẹ ra, lo ba ji owo onikẹmiisi gbe n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Arakunrin kan, Adedigba Jẹrimaya, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ kan niluu Ilọrin bayii. Owo Arabinrin Ọladuntoye Toyin to n ta oogun oyinbo ni ṣọọbu Kẹmiisi kan lagbegbe Ganmọ, niluu Ilọrin, lo lọọ ji gbe, niyẹn ba fi ọlọpaa mu un.

L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Insipẹkitọ ọlọpaa, Iwaloye Adulwahab, sọ fun ile-ẹjọ pe ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun 2022, ni Toyin pe ileeṣẹ ọlọpaa pe ọwọ tẹ afurasi ole kan, Adedigba Jẹrimaya, to ji oun ni ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogoji Naira (36,000), ninu sọọbu oun lasiko ti oun n sun lọwọ. Asiko naa loun sare taji, toun si pariwo ole, lawọn araadugbo fi tete ba oun le e mu ko too sa lọ.

Jẹrimaya loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an tori pe oogun ara yunyun ni oun lọọ ra ni ṣọọbu kẹmiisi naa. O ni oun ba iya kẹmiisi yii to n sun loootọ, oun si ji iya naa, ṣugbọn sadeede ni iya yii pariwo ole le oun lori, ti gbogbo adugbo si pe le awọn lori, wọn lu oun bii aṣọ ofi, lẹyin naa ni wọn fi ọlọpaa mu oun. O tẹsiwaju pe ẹgbẹrun meji aabọ Naira pere ni wọn ba lapo oun, ti wọn si ko gbogbo owo naa pata. Afurasi naa fi kun un pe iṣẹ birikila loun n ṣe nipinlẹ Jos, ṣugbọn ọmọ bibi Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ni oun, oun si gbe ilu naa die koun too maa waa gbe n’Ilọrin, ni bii ọdun meji sẹyin.

Onidaajọ Lawal Ajibade beere lọwọ afurasi boya kẹmiisi yẹn nikan lo sun mọ ile rẹ ju? Ṣe o ti ra oogun lọdọ iya yii ri tẹlẹ abi ṣe awọn ọga birikila miiran to wa ni agbegbe naa da a mọ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ birikila? Gbogbo ibeere yii ni Jẹrimaya dahun si lọkọọkan. O ni ki i ṣe ṣọọbu iya naa lo sun mọ ile oun ju, o ni oun ko ra oogun lọdọ iya naa ri, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ birikila mọ oun lagbegbe naa daadaa gẹgẹ bii ọkan lara ọmọ ẹgbẹ naa.

Adajọ Lawal Ajibade paṣẹ pe ki wọn gba beeli Jẹrimaya pẹlu ẹlẹrii meji, ọkan gbọdọ jẹ mọlẹbi rẹ, nigba ti ẹni keji gbọdọ jẹ alaga ẹgbẹ birikila.

Leave a Reply