Oogun awọro ni mo fi ori ati apa Moses ti a pa ṣe, a si ta ọkàn rẹ ni ẹgbẹrun  marun-un naira- Ifadare

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ifadare Afolabi, oloye Ogboni kan to fi ilu Ikirun, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Ọṣun, ṣebujoko, ti sọ pe ki awọn eeyan le maa wọ wa sinu tẹmpili oun loun ṣe lẹdi apo pọ mọ ọrẹ oun, Ifaṣeun Afọlabi, lati pa ọmọkunrin kan to fẹẹ ṣe aajo owo.

Ifadare ṣalaye pe onibaara Ifaṣeun ni Faṣesan Ayọade Moses, ẹni ọdun marunlelọgbọn, oogun owo lo si wa lọ sọdọ Ifaṣeun ti awọn fi pinnu lati pa a, ti awọn si ge ẹya-ara rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Lasiko to n ka boroboro bii ẹyẹ ibaka ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa niluu Oṣogbo ni Ifadare sọ pe ẹmi eṣu lo ti oun lati huwa naa nitori oun ko ṣe iru rẹ ri latigba ti oun ti n ṣiṣẹ awo.

O sọ siwaju pe oun ko mọ Moses tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti Ifaṣeun sọ foun pe o fẹẹ ṣoogun owo lawọn mejeeji jọ pinnu lati lo o.

“Mi o ṣe iru rẹ ri laye, n ko si mọ iru ẹmi to ti mi lati gbimọ-pọ pẹlu Ifaṣeun lati huwa yii lọjọ naa. Bi a ṣe pa a tan ni mo ge ori ati apa rẹ, oogun awọro ni mo si fi ṣe.

“Ohun to ya mi lẹnu ju ni pe oogun yẹn ko ṣiṣẹ, n ko si mọ idi to fi ri bẹẹ. Ṣe ni tẹmpili ti mo ti maa n ṣiṣẹ da paroparo titi di ọjọ ti awọn ọlọpaa waa mu mi”

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, sọ pe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun yii, ni iya to bi Moses lọọ sọ fawọn ọlọpaa pe oun ko ri ọmọ oun.

Ọlọkọde ṣalaye pe bi awọn ọlọpaa ṣe bẹrẹ iwadii ni ọwọ tẹ Ifaṣeun, bo tilẹ jẹ pe o sọ pe oun da Moses mọ, ṣugbọn o ni oun ko mọ ibi to wa.

Nigba ti itọsẹ dun un daadaa, o jẹwọ pe oun ati Ifadare pẹlu Ifadare Afọlabi ati Taiwo lawọn pa ọmọkunrin naa ninu ile kan lagbegbe Fidibomi, niluu Ikirun.

Ọlọkọde fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti ọwọ tẹ Ifadare lawọn mejeeji jẹwọ pe awọn ta ọkan (heart) ọmọkunrin naa ni ẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira fun Adeleke Kabiru, awọn si ta ẹya-ara kọọkan fun Oloyede Moruf, Oseni Mukaila ati Badmus Sairu, ki wọn too sin ageku rẹ sinu igbo.

Kọmiṣanna sọ siwaju pe awọn ti hu oku Moses, iya rẹ si fi aṣọ to wọ gbéyin da a mọ, bẹẹ lawọn ti gbe e lọ sile igbokuu-si ọsibitu UNIOSUN.

O ni lẹyin iwadii ni gbogbo wọn yoo foju bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply