Adewale Adeoye
Bi wọn ba leeyan rugi oyin, ti wọn leeyan wọ wahala nla, babalawo kan torukọ rẹ n jẹ Timothy Dauda, ẹni ọdun mọkandinlogun, to yinbọn pa onibaara rẹ lasiko to n dan oogun ayẹta ibọn wo lara rẹ ni wọn n wi.
Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Onumu, nijọba ibilẹ Akoko-Edo, nipinlẹ Edo, ni babalawo naa to loun jogun oogun ayẹta ibọn lọwọ baba-baba oun wa bayii, o n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn.
ALAROYE gbọ pe ọkan lara awọn onibaara rẹ, Oloogbe Alex Ezekiel, lo fẹẹ ṣe oogun ayẹta ibọn fun, lẹyin to loun ti pari oogun naa tan, lo ba ni k’oun dan an wo lara onitọhun, niwọn igba to jẹ pe ẹni naa lo fẹẹ lo o. O doju ibọn ṣakabula ọwọ rẹ kọ ọ, lo ba yinbọn naa gbau fun Alex. Eyi ti ọta ibọn naa iba fi da silẹ wẹẹrẹwẹ, ti ko si ni i turun kan lara ẹni to yin in mọ, niṣe ni oloogbe ṣubu lulẹ gbalaja, to si ku patapata.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, S.P Moses Joel Yamu, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe awọn ọlọpaa agbegbe Igarra, lo fọwọ ofin mu afurasi ọdaran yii, ti wọn si sọ ọ sahaamọ wọn fun iwa to lodi sofin to hu.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe ‘‘Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni iṣẹlẹ naa waye, Oloogbe Alex Ezekiel lo lọọ ba afurasi ọdaran to jẹ babalawo, Timothy, pe ko ba oun ṣoogun ayẹta ibọn. Lẹyin ti babalawo yii pari oogun ayẹta naa tan lo ba dan an wo lara oloogbe yii, ṣe lo yinbọn naa fun un nibi ti ko ti daa, ti iyẹn si ṣubu lulẹ gbalaja loju-ẹsẹ, ko duro gba ikeji rara. Wọn sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan to n jẹ Ifelaja Hospital, ṣugbọn awọn dokita ko gba oloogbe naa lọwọ wọn rara, wọn lo ti ku ki wọn too gbe e de ọdọ awọn.
Alukoro ni awọn n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun lọwọ, tawọn si maa foju babalawo naa bale-ẹjọ laipẹ yii, ko le fimu kata ofin fohun to ṣe.