Oogun ayẹta ti Yusuf ṣẹṣẹ ṣe lo fẹẹ dan wo tọmọ ẹ fi yinbọn pa a

Monisọla Saka

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla yii, lọkunrin kan, Yusuf Adamu, dero ọrun nipinlẹ Adamawa, lẹyin to ni ki ọmọ oun ọkunrin yinbọn si oun wo fun oogun tuntun toun ṣẹṣẹ ṣe.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa ṣẹṣẹ kowo ṣe oogun ayẹta kan ni, tawọn to ṣe e fun un si ti fi da a loju pe ko si iru ibọn ti wọn le yin mọ ọn ti yoo ran an to ba ti le fi oogun naa sara.

Oogun naa ni ọkunrin yii gbe lọ sile, to si pe ọmọ ti iyawo ẹ waa gbe fẹ ẹ, Suugbomsumen Adamu, lo ba paṣẹ fun un pe ko wọle lọọ gbe’bọn, ko yin in si oun, nitori agbara oun tun ti lekan si i, ko si si bi ibọn naa ṣe le lagbara to, ko le wọle soun lara pẹlu oogun ajẹbiidan tuntun toun ṣẹṣẹ ṣe yii.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ti fidi iṣẹlẹ to waye niluu Sankipo, nijọba ibilẹ Jada, nipinlẹ ọhun mulẹ.

Ninu ọrọ ẹ, Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, Suleiman Nguroje, ni awọn ti mu ọmọkunrin to yinbọn naa si akata awọn. O fi kun un pe awọn agbofinro yoo ṣe iwadii daadaa lati ri i daju pe wọn dajọ naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, lai wo iru ajọṣepọ to wa laarin oloogbe ati ẹni to yinbọn pa a.

Leave a Reply