Jide Alabi
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ti ke si Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, lati gba ijọba Makinde laaye ko ṣiṣẹ ẹ gẹgẹ bii olori alaabo nipinlẹ Ọyọ.
Ọoni Ifẹ sọ pe lootọ ni Sunday Igboho ti ṣiṣe akikanju nipa bo ṣe dide lati ja fun awọn eeyan ẹ, bẹẹ ni awọn ti awọn jẹ ọba alaye yin in paapaa, ṣugbọn bi ọrọ ṣe n lọ yii, ẹtọ ni ko ṣe pẹlẹpẹlẹ, ko ma sọ ara ẹ di ẹni to ga ju ofin lọ, niwọn igba ti awọn alaṣẹ ṣi wa nipo nipinlẹ naa.
O ni, “Gbogbo wa la dunnu lori ohun to o ṣe, ṣugbọn nisinyii ti Gomina Ṣeyi Makinde ti lọọ ri Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ yii, ojuṣe ẹ ni ko o faaye silẹ fun gomina, ẹni ti i ṣe olori alaabo nipinlẹ Ọyọ lati maa ba iṣẹ ẹ ̀lọ. Ohun to dara ni Sunday Igboho gbe dani, bẹẹ lo gbọdọ ṣọra daadaa ki awọn oloṣelu ma lọọ sọ ọ di nnkan mi-in mọ ọn lọwọ.”
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ meje pere ni Sunday Igboho fun awọn Fulani darandaran ti wọn wa lagbegbe Ibarapa ki wọn fi kuro nibẹ pẹlu awọn nnkan ọsin wọn.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe, bẹẹ ni wọn n fipa ba obinrin wọn sun, ti wọn si tun n ba awọn nnkan oko wọn jẹ.
Bi ọjọ meje ṣe pe ni Igboho atawọn ọmọlẹyin ẹ ko ija lọọ ba awọn Fulani, ti pupọ ninu wọn si fẹsẹ fẹ ẹ nigba ti wọn gburoo ogun tiyẹn n gbe bọ waa ka wọn mọ.