Florence Babasola
Arole Oduduwa, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti bẹrẹ igbele ọlọdọọdun eleyii to maa n ṣapẹẹrẹ ibẹrẹ ọdun Ọlọjọ niluu Ileefẹ.
Alẹ ana, Sannde, ni Ọọni kọja si Ile-Mọlẹ to wa ni Irẹmọ quarters ni Ileefẹ, yoo si lo ọjọ meje nibẹ lai ba ẹnikẹni sọrọ ju gbigba adura lọ
Bi Ọọni ṣe n jade nilu Ile Oodua ti aafin rẹ wa lo sọ fun awọn oniroyin pe oun yoo lo asiko igbele naa lati ba Olodumare sọrọ lori ajakalẹ arun korona, ki ogun rẹ le ṣẹ patapata.
O ni asiko naa yoo wa fun aawẹ ati adura gẹgẹ bi awọn baba-nla rẹ ṣe maa n ṣe ati lati fi ṣipẹ pe ki ajakalẹ arun tabi wahala mi-in ma ṣe tun wọnu orileede yii mọ.
Lẹyin ti Ọọni ba kuro ni igbele ni oniruuru ayẹyẹ ti wọn ti la silẹ fun ọdun ọlọjọ yoo bẹrẹ, ti gbigbe ade Aare ti Ọọni yoo fi gbadura fun gbogbo orilẹ-ede yoo si kadii rẹ nilẹ.
Lasiko ti Ọọni ba de ade naa ni yoo kọja lawọn ikorita kan to ṣe pataki bii Ita Ọranfẹ, Ita Agbansala ati Ita Okemogun nibi ti adura pataki yoo ti maa waye.