Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ Rahman Oṣodi, tile-ẹjọ akanṣe to n ri si lilo awọn ọmọde nilokulo ilu ‘Special Offences Court’, to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn foju alagba ṣọọṣi kan, Ọgbẹni Wilfred Kon Ukah, ẹni ọdun mejilelaaadọta ba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ba ọmọdebinrin kan, Omidan Janet, ti ko ju ọdun mejila sun nile awọn obi rẹ.
Ṣe lawọn ero to wa ni kootu lọjọ naa bu sẹrin-in gbaragada nigba ti akọwe kootu pe olujẹjọ sita, ṣugbọn to n gbọn lọwọ gbọn lẹsẹ bii mọto alupupu.
Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Godwin, toun naa wa nile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, nigba ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ sọ niwaju adajọ pe, ‘‘Oluwa mi, teṣan Ẹlẹmọrọ, lagbegbe Badoore, niluu Ajah, nipinlẹ Eko, ni mo wa lọjọ ti Ọgbẹni Sunday, ti i ṣe baba Janet ti olujẹjọ fipa ba sun waa fọrọ ọhun to wa leti. Sunday, iyawo rẹ atawọn kọọkan ti wọn jẹ araale kan naa, nibi ti olujẹjọ ti hu iwa palapala naa ni wọn jọọ kora wọn wa si teṣan wa lọjọ naa, wọn wọ Sunday wa pe, o fipa ba ọmọ ọdun mejila sun. A gba ọrọ lẹnu rẹ atawọn tọkọ-taya ti wọn mu un wa, ninu ọrọ wọn ni wọn ti sọ pe oore lawọn ṣe fun olujẹjọ nipa bawọn ṣe faaye gba a pe ko maa gbe lọdọ awọn, niwọn igba to jẹ pe pasitọ ni.
‘’Omidan Janet ti olujẹjọ fipa ba sun sọ pe aimọye igba ni olujẹjọ ti fipa ba oun lo pọ sun ninu ile awọn obi oun, ṣugbọn ti Sunday ni ẹẹmeji pere ni eṣu gbọwọ oun lo pẹlu ọmọ naa. A ba olujẹjọ ko gbogbo ọrọ rẹ silẹ, a si ka a si i leti ko too di pe o tọwọ bọwe yii. Lẹyin naa la taari rẹ lọ si Panti, nipinlẹ Eko, ki wọn le maa ba a ṣẹjọ lọ. Ṣugbọn ọrọ olujẹjọ yatọ si alaye ti Insipẹkitọ Godwin sọ nile-ẹjọ o’’.
Nigba to n fesi si ẹsun ti wọn fi kan an, alagba ijọ naa ṣalaye pe ‘‘Oluwa mi, irọ po ninu ẹsun awuruju ti agbofinro ọhun fi kan mi o. Akọkọ na, mi o ki i ṣe pasitọ rara, alagba ni mi ninu ijọ ti mo n lọ, mo kan maa n tẹle awọn pasitọ kaakiri ni. Ẹẹkeji ni pe ki i ṣe ile awọn to mu mi lọ si teṣan ni mo n gbe gẹgẹ bii ẹsun ti wọn fi kan mi.
Lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni mo deede ri Ọgbẹni Sunday ti i ṣe baba ọmọ ti wọn ni mo ba sun niwaju geeti ile ti mo n gbe l’Ojule karun-un, Opopona Laara, ni Ibeju Lekki, nipinlẹ Eko, wọn n pariwo gee le mi lori pe mo fipa b’ọmọ wọn sun, ki n too sọrọ, ṣe ni wọn wọ mi bọ sita, wọn lu mi bii baara lọjọ naa, wọn si wọ mi lọ sọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Ẹlẹmọrọ, niluu Badoore Ajah. Awọn ọlọpaa yii ko jẹ ki awọn kan ti wọn mọ pe iṣẹ ọwọ mi mọ, ti wọn tẹle mi lọ si teṣan duro rara, wọn le gbogbo wọn pata sita ni, emi ati awọn obi ọmọ naa nikan la wa lọdọ awọn ọlọpaa. Obi ọmọ naa kọwe, ṣugbọn wọn ko jẹ ki emi kọ temi rara, awọn ọlọpaa lo kọwe fun mi, bẹẹ ni wọn fipa ni ki n kọwọ-bọwe lẹyin ti wọn ka ohun ti wọn kọ silẹ setiigbọ mi tan, mi o mọ boya ootọ lohun ti wọn ka si mi leti tabi irọ ni. Wọn lu mi bajẹ lọdọ wọn, ọjọ mẹjọ gbako ni mo lo lọdọ awọn ọlọpaa naa ko too di pe wọn mu mi lọ sọdọ awọn ọlọpaa Panti. Iya naa pọ gan-an fun mi ni o, mi o si figba kankan sọ pe ẹẹmeji ni mo b’ọmọ naa sun ni gbogbo asiko ti mo fi wa ni teṣan ọlọpaa rara.
Agbẹjọro ijọba beere ọrọ lọwọ olujẹjọ pe, ‘Ẹẹmelo gan-an ni wọn lu ọ ni teṣan ọlọpaa ati pe ki lo de ti o o ṣe kọ iwe naa funra rẹ dipo to o fi gba eyi ti wọn kọ’.
Olujẹjọ ni, ‘mi o figba kankan sọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn ba mi kọwe o, awọn ni wọn kọ ọ funra wọn, nigba ti wọn kọ ọ tan ni wọn ni ki n ka a, ṣugbọn mo sọ fun wọn pe mi o mu jidi oju mi dani, pe mi o le ri ohun ti wọn ba mi kọ ka rara. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju, ọdun 2020 ni mo deluu Eko, lẹyin ọdun kan niyawo mi de sọdọ mi, mi o figba kankan nipenija ile gbigbe ri, ile ti mo n gbe naa ni wọn ti waa mu mi, awọn olopaa Ẹlẹmọrọ, niluu Badoore Ajah, ni wọn kọkọ fi lilu ba temi jẹ ko too di pe wọn mu mi lọ sọdọ awọn ọlọpaa Panti.
Adajọ sun igbejo si ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii, o ni ki agbefọba mu iwe ti dokita fun wọn lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe f’ọmọ naa wa sile-ẹjọ lati mọ boya loootọ ni wọn fipa ba a sun.
Bakan naa lo ni ki wọn da olujẹjọ pada sọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, titi di asiko ti igbẹjọ maa fi waye.