Oore nla de fun Iyabọ Ojo, Jaiye Kuti ati Bọsẹ Akinọla

Lọla Ojo

Beeyan ba gẹṣin ninu awọn oṣere ilẹ wa mẹta kan, o daju pe tọhun ko ni i kọsẹ, nitori ninu idunnu rẹpẹtẹ ni wọn wa lasiko yii, gbogbo eeyan lo si n ba wọn dawọọ idunnu ọkan-o-jọkan oore ti Ọlọrun ṣe fun wọn.

Ẹni akọkọ to ṣubu lu ire ninu awọn oṣere yii ni arẹwa obinrin to lomi lara daadaa nni, Jaiye Kuti. Ileeṣẹ ti obinrin abeji jo raisi naa n ṣoju fun ni wọn gbe ọkọ ayọkẹlẹ…..(the name of the car) bọginni kan fun un lọsẹ to kọja yii, wọn ni ko maa fi ṣe ẹsẹ rin. Ṣe bi awo ba ki fun ni, a a ki fawo naa pada ni, eyi lo ṣokunfa mọto ti wọn gbe fun oṣere naa, wọn ni awọn mọ asiko to jẹ aṣoju ileeṣẹ awọn si daadaa.

Bo tilẹ jẹ pe oṣere yii ko pariwo ọkọ naa rara, ṣugbọn awọn to sun mọ ọn bii iṣan ọrun, ninu eyi ti oṣere ẹgbẹ rẹ, Bimbọ Ọṣhin wa ni wọn n ki i ku oriire, ti wọn si n ṣadura fun un pe ọkọ naa ko ni i fori sọgi, bẹẹ ni ko ni i gba ẹjẹ rẹ.

Iroyin eyi lo n lọ lọwọ ti wọn fi tun kede Bọsẹ Akinọla, arẹwa oṣere to fi lu Ibadan ṣebugbe nni, pe oun ni alaga ẹgbẹ awọn oṣere tiata, iyẹn TANPAN, ẹka ti ilu Ibadan. Lọsẹ ta a ṣẹṣẹ pari yii ni eto idibo waye niluu Ibadan, nibi ti Bọsẹ to ṣẹṣẹ ṣe fiimu kan ti wọn n pe ni ‘Aranda Ẹkun’ ti jawe olubori.

Latigba naa lawọn eeyan ti n ki oṣere to niwa pẹlẹ naa ku oriire, ti wọn si n gbadura fun un pe ara rere ni yoo fi lo ipo naa.

Bakan naa ni idunnu tun ṣubu layọ lọdọ oṣere ilẹ wa ti ko gba nọnsẹnsi nni, Iyabo Ojo. Funran oṣere yii lo kede pe oun ti ni ade ori tuntun, ko si le pa idunnu rẹ mọra nigba to n kede pe ọkunrin ti oun ṣẹṣẹ fẹẹ fi ṣe ade ori yii ki i ṣe Yoruba o, o ni ilẹ Ibo lo ti wa.

Iyabọ kọ ọ sori Instagraamu rẹ pe: ‘‘Mo dupẹ lọwọ rẹ, Obim, fun bi o ṣe fẹran mi gidigidi, ti o si ru ọkan mi soke. Chei, ọmọ Ibo ti gba ọkan ọmọbinrin Yoruba yii.’’.

Ṣugbọn bi Iyabọ ti kọ ọrọ yii sori ikanni rẹ ni awọn kan ti n yọnu ṣi i pe ṣe ki i ṣe ọkọ ọlọkọ o, ṣe ki i ṣe ọkunrin to ti niyawo nile ni oṣere naa fẹẹ fẹ. Oju-ẹsẹ lo si ti da wọn loun pe ‘emi ko fẹ ọkọ ọlọkọ o, ọkunrin ti mo fẹẹ fẹ ko ti i niyawo nile’.

Bakan na ni awọn oṣere ẹgbẹ rẹ pẹlu awọn ololufẹ re ti n ki i ku oriire. Ọkan ninu awọn to ti ki oṣere yii ni Toyin Abraham, ẹni to kọ ọ sisalẹ ikede ti Iyabọ ṣe pe’ẹyin ti ẹ n ta aṣọ, ẹ ba mi wa aṣọ ti owo rẹ wọn ju lọ’ O ni asọ ilu awọn Ibo ti wọn n pe ni jọọji to ba rẹwa daadaa, to si wọn lowo ni ki wọn ba oun wa, nitori iyawo awọn ni Iyabọ.

Ọjọ ti iwe ipe yoo jade, ti aṣọ ẹbi paapaa yoo jade, ti igbeyawo naa yoo waye ni awọn ololufẹ rẹ n duro de.

Leave a Reply