Ọpa epo bẹntiroolu lawọn eleyii n fọ tọwọ fi tẹ wọn

Adeoye Adewale

Ọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orile-ede wa kan ti wọn n pe, ni ‘6 Division Garrison’, eyi to wa niluu Portharcourt,  nipinlẹ Rivers, ti sọ pe mejila lara awọn ọdaran kan to jẹ pe igba gbogbo ni wọn maa n lọọ fọ ọpa epo bẹntiroolu, ti wọn aa si ji epo fa nibẹ, ni ọwọ palaba wọn ti ṣegi bayii, tawọn si ti n ṣewadii lori ibi ti wọn n ta awọn epo ọhun si, kawọn le lọọ fọwọ ofin mu gbogbo awọn ẹni ibi to n ba wọn ṣiṣẹ pọ ọhun.

Ọgagun Eddy Effiong to jẹ ọga ikọ awọn ṣọja to lọọ fọwọ ofin mu awọn ọdaran naa sọ fawọn oniroyin lakooko to n ṣafihan wọn pe ọjọ keji si ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun yii, lọwọ tẹ awọn ọdaran naa lagbegbe kan ti wọn n pe ni, Rumuekpe-Okporowo, nitosi ilu kekere kan ti wọn n pe ni, Okoba, nijọba ibilẹ Ahoada East.

Lara awọn ẹru ofin ti wọn sọ pe wọn ba lọwọ awọn ọdaran ọhun ni kẹẹgi ti wọn fi n ko epo bẹntiroolu naa si, maṣinni alupupu oriṣiiriṣii, akanṣe apo kan to nipọn daadaa, ti wọn tun n lo lati maa fi gbe epo bẹntiroolu naa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

ALAROYE gbọ pe ọjọ  ti pẹ tawọn ọdaran ọhun ti wa lẹnu iṣẹ buruku yii, ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.

Ọga awọn ṣọja ọhun sọ pe iye epo bẹntiroolu ti awọn ba lọwọ awọn ọdaran ọhun ko ṣee fẹnu sọ rara.

O ni, ‘‘A ti fọwọ ofin mu awọn ọdaran kan to jẹ pe igba gbogbo ni wọn fi maa n ji epo bẹntiroolu ilẹ wa gbe. A maa too fa wọn le ọlọpaa agbegbe ta a ti mu wọn lọwọ, ki wọn le ba wọn ṣẹjọ.

Bi wọn ba sọ pe awọn ko ni i gbọ, awa paapaa ko ni i gba fun wọn rara. A mọ  pe awọn to n ji epo ọhun pọ daadaa lagbegbe Niger/Delta, ta a si maa n fọwọ lile mu gbogbo wọn nigba gbogbo.

 

Leave a Reply