Lẹyin ti wọn sanwo nla, awọn mẹrin ti wọn ji gbe l’Ekiti gbominira

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Lẹyin ti wọn san miliọnu mẹrin Naira, awọn ara Ibadan mẹrin ti awọn agbebọn ji gbe n’Irele-Ekiti lopin ọsẹ to kọja yii ti gba iyọnda.

Awọn mẹrin naa ti wọn wa lati Ibadan lati waa ṣe ayẹyẹ kan nipinlẹ Kogi ni wọn ji ko, ti wọn si ko wọn wọ inu igbo kan ni agbegbe naa, nigba ti wọn n dari bọ lati ibi ayẹyẹ ọhun.

Awọn ajinigbe naa ti kọkọ pe awọn mọlẹbi awọn eeyan naa, ti wọn si beere miliọnu mẹwaa Naira ki wọn too le tu wọn silẹ, ṣugbọn awon mọlẹbi wọn bẹ wọn si miliọnu mẹrin Naira.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọga awọn Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe oun ti gbọ pe wọn ti tu awọn ti wọn ji ko naa silẹ pẹlu ibẹru.

Kọmọlafẹ sọ pe oun ko gbọ boya wọn san owo ki wọn too tu wọn silẹ, ṣugbọn awọn ọmọ ogun oun ati awọn ọdẹ ibilẹ ti wọn wa ni agbegbe naa ni wọn ṣiṣẹ takuntakun ki wọn too gba iyọnda.

Leave a Reply