Monisọla Saka
Ori ti ko awọn akẹkọọ ileewe giga Confluence University of Science and Technology, Osara, Okene, nipinlẹ Kogi, yọ. Awọn oṣiṣẹ eleto aabo atawọn fijilante adugbo lo gba wọn silẹ ninu igbekun ti wọn wa.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Kingsley Fanwo, ti i ṣe kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ naa sọrọ ọhun di mimọ.
O ni awọn ẹṣọ alaabo atawọn fijilante ti wọn doju ibọn kọ awọn ajinigbe ọhun ni agbara wọn ka awọn ọdaju ẹda naa. Nigba ti ọwọ dun awọn ajinigbe yii ni wọn fẹyin rin pada, ti pupọ wọn si gbe oju ọgbẹ ibọn lọ lai duro wo awọn ọmọ ti wọn ji gbe.
Iro ibọn to n kọ lala yii, ni wọn lo mu awọn akẹkọọ naa fọn pẹẹrẹpẹ kaakiri inu igbo, lati le sa asala fun ẹmi wọn lọwọ aṣita ibọn.
Bo tilẹ jẹ pe mẹsan-an ni Fanwo darukọ lasiko ti wọn n kede pe awọn agbebọn ji wọn ko, awọn mẹrinla ni akẹkọọ ti wọn ri gba silẹ nibuba awọn ajinigbe ọhun.
O ni, “A gboṣuba kare fawọn ọdẹ ibilẹ atawọn oṣiṣẹ eleto aabo fun iwa akin ati igboya wọn. Ọpẹ pataki lọwọ awọn oṣiṣẹ DSS, fun ọgbọn inu ti wọn lo, ati iwa akinkanju wọn.
Awọn oṣiṣẹ alaabo ti tun fi idi ti ipinlẹ Kogi ko fi ni i jẹ ibi idẹkun tawọn agbebọn, ajinigbe atawọn oniwa laabi mi-in le maa gbe han lẹẹkan si i.
“Lara aṣeyọri ti wọn ti ṣe latigba yii wa jẹ ẹri pe Gomina Ahmed Usman Ododo, ti ipinlẹ Kogi ti ṣetan lati ma ṣe fi ọwọ hẹrẹ-hẹ-n-hẹ mu ọrọ eto aabo fawọn eeyan ipinlẹ Kogi.
A n rọ araalu lati fẹjọ ẹnikẹni ti wọn ba ri pẹlu oju ọgbẹ ibọn ni agbegbe wọn to awọn ẹṣọ alaabo leti.
Bakan naa ni SP William Aya, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Kogi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Mẹrinla ni awọn akẹkọọ to ni awọn ẹṣọ alaabo doola lasiko ti wọn doju ija kọ awọn atilaawi.
O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe, to fi mọ fijilante kan, ati oṣiṣẹ DSS kan ti wọn fara pa ni wọn ti wa nile iwosan, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ. O ni awọn oṣiṣẹ alaabo ko ti i dawọ iṣẹ duro, nitori gbogbo inu igbo ọhun ni wọn ṣi n gbọn yẹbẹyẹbẹ lati ri i daju pe awọn akẹkọọ mi-in ti wọn ba ṣẹku sibẹ yoo dari dele layọ.
Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn ni awọn agbebọn naa ṣadeede ya wọnu kilaasi tawọn akẹkọọ yii ti n kawe, ni igbaradi fun idanwo saa akọkọ wọn ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu yii.
Niṣe ni wọn ni awọn ajinigbe yii da ibọn bolẹ, nibẹ ni wọn si ti ko awọn akẹkọọ tọwọ wọn ba wọnu igbo lọ.