Monisọla Saka
Beeyan ba gẹṣin ninu ọkan ninu awọn agba oṣere ilẹ wa, Fatai Adekunle Adetayọ Oodua, ti gbogbo eeyan mọ si Lalude, ko ni i kọsẹ rara. Eyi ko ṣẹyin bi baba naa ṣe darapọ mọ awọn to n fi mọto ṣe ẹsẹ rin pẹlu iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu kan.
Ọkunrin to ti wa nidii iṣẹ tiata lati bii ọgbọn ọdun o le yii, ni Kamọ_state, ọkunrin alawada ori ayelujara kan sọ pe ko wu oun bi agba ọjẹ onitiata naa ko ṣe maa fi mọto ṣe ẹsẹ rin, to jẹ pe niṣẹ lo maa n gan mọto kaakiri.
Alaye ti Kamọ ṣe ni pe, latọjọ toun ti n pe baba si ere, oun ko mọ pe ọkọ ero ni wọn maa n wọ wa si ibikibi tawọn ba ti fẹẹ ya iṣẹ. Amọ nigba toun ti mọ bayii, idunnu oun ni ki baba naa di ẹni ti yoo ni ọkọ ara ẹ, ṣugbọn oun nilo iranlọwọ awọn ololufẹ baba naa. Idi niyi to fi pe awọn ololufẹ ọkunrin naa pe ki awọn jọ dawo jọ lati ra mọto olowo kekere ti ko ni i maa da a laamu fun un. Ọkunrin yii lo kọkọ ko miliọnu kan Naira silẹ, tawọn alaaanu mi-in naa si tun da miliọnu mẹta Naira kun un lati fi ra ọkọ ayọkẹlẹ fun baba naa, lọjọ ti Kamọ funra ẹ n ṣe ọjọ ibi rẹ.
Ni bayii, awọn ololufẹ Lalude ti mu inu rẹ dun pẹlu bi wọn ṣe ra moto Toyota Camry alawọ pupa to rẹwa daadaa fun un. Nigba ti Kamọ_state n ṣafihan mọto ọhun fun Lalude, niṣe ni oṣere naa di mọ ọn, to si bẹrẹ si i ṣadura fun un. Lẹyin eyi lo dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ ti wọn ko pariwo ara wọn sita, ṣugbọn ti wọn dawo naa jọ lati pese mọto ọhun.
Ninu idupẹ rẹ, Lalude ni, ‘’Ṣe ẹ ti ri nnkan bayii, oju ẹni la ti i mọ akusin ẹni, ṣe ẹ ri i pe a ko ti i ku bayii. Walai, mo ṣaarẹ kan lọdun kan, mi o jẹ ki ara ile keji gbọ, fun odidi oṣu mẹjọ ni mo fi ṣaarẹ naa, ti n ko si jẹ ki ẹnikẹni gbọ pe mo ṣaisan. Mo dupẹ lonii pe ki i ṣe owo aarẹ ni mo beere lọwọ yin, ẹ ko fun mi lowo iku, owo ire lẹ fun mi’’.
Ninu ọrọ ti Kamọ kọ sabẹ fidio naa lo ti ni, “Lọsẹ to kọja, mo gba a lero lati ra mọto fun Baba Lalude, amọ nitori ti mi o le da a ṣe, mo ke sawọn ọrẹ atawọn alatilẹyin mi lori ẹrọ ayelujara Facebook. Pẹlu iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ati atilẹyin ọmọ iya mi daadaa kan, iyẹn Temilọla Ṣobọla, toun naa ba wa gbe fidio naa fawọn aye ri, baba ti di onimọto, wọn si mọ ọn loore o.
“Lonii ti mo n ṣe ọjọ ibi mi ni Baba Lalude di onimọto. Koko ọrọ ni pe, ẹ jẹ ka maa mọ riri awọn eeyan pataki wa, ka si maa ṣe nnkan daadaa fun wọn, nigba ti wọn ba ṣi wa laye ati ninu alaafia”.
Bayii ni Lalude dupẹ lọwọ awọn to ṣe e loore banta banta yii. Awọn ololufẹ Lalude, awọn afẹnifẹre atawọn oṣere tiata bii Toyin Tomato, Jumọkẹ George, atawọn mi-in bẹẹ ni wọn ti ba Lalude yọ, wọn ni ẹmi rẹ yoo lo o, ole ko si ni i gbe e.