Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin CAC, Oke-Igan, to wa niluu Akurẹ, ti wọn bọ sọwọ awọn ajinigbe lagbegbe Ẹlẹgbẹka, nitosi Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, la gbọ pe wọn ti jaja bọ lọwọ awọn to ji wọn gbe.
Ohun ti ALAROYE gbọ, ṣugbọn ti a ko ti i fidi rẹ mulẹ fun wa ni pe awọn eeyan ọhun lawọn janduku agbebọn naa tu silẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lẹyin ti wọn ti sanwo nla fun wọn.
Ni ibamu pẹlu alaye ti alaboojuto ẹkun Odubanjọ ti i ṣe olu gbogbo CAC nipinlẹ Ondo, Pasitọ Akanni, ṣe fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, ti iṣẹlẹ yii waye, o ni awọn mẹsan-an ni wọn si wa ninu igbekun awọn agbebọn, awọn mẹjọ lo ni wọn ti raaye sa asala, nigba to si ku mẹta ninu awọn eeyan ọhun ti awọn si n wa.