Ọpẹ o! Ija pari laarin awọn afọbajẹ Ibadan, Ladọja loun ko ba wọn ṣẹjọ mọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ko sohun to n di wọn lọwọ lati fi ọba tuntun jẹ n’Ibadan mọ bayii pẹlu bi Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja, ti ṣe gbe ẹjọ to pe ijọba ipinlẹ Ọyọ atawọn afọbajẹ ẹgbẹ ẹ si kootu kuro.

Ladọja, to tun jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, lo pẹjọ ta ko atunto ti ijọba ṣe lori ọrọ oye ilẹ Ibadan, eyi to sọ awọn agba ijoye ilẹ Ibadan di ọba alade.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2023, l’Olubadan ana, Ọba Lekan Balogun, pẹlu atilẹyin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi awọn agba ijoye ilẹ Ibadan jọba, yatọ si Ladọja, ẹni to finnu findọ sọ pe oun ko jẹ iru ọba bẹẹ, Olubadan ilẹ Ibadan nikan loun fẹẹ jẹ.

Bẹẹ lawọn igbimọ Olubadan yooku di ọba alade, ti Ladọja nikan ko si kuro nipo agba ijoye lasan. Latigba naa lawọn yooku ti ri gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ naa gẹgẹ bii ẹni to kere si wọn ninu ipo, wọn gba pe odidi ọba ki i ṣẹgbẹ ijoye ilu.

Bo si tilẹ jẹ pe Ọtun Olubadan yii lo yẹ ko pe ipade gẹgẹ bii ẹni ti ipo rẹ ga ju lọ ninu igbimọ awọn afọbajẹ ilẹ Ibadan bayii, sibẹ, awọn afọbajẹ yooku ko da a lohun nigba to pe wọn fun ipade lati yan Ọlakulẹhin gẹgẹ bii Olubadan tuntun, ko sẹni to da a lohun, wọn gba pe agba ijoye lasan loun, iwa arifin lo jẹ fun un lati maa ranṣẹ pe awọn odidi ọba waa ṣepade pẹlu oun.

Ọtọ ni wọn kọkọ fa ọrọ yii laarin ara wọn ko too di pe wọn ri i yanju, ti wọn fi pada lọ sibi ipade ti baba naa pe lẹẹkeji. Ninu ipade ọhun naa ni wọn ti fọwọ si Ọlakulẹhin gẹgẹ bii ẹni naa to kan bayii lati gori apere Olubadan, ti  wọn si fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba.

O yẹ kijọba ti fọwọ si orukọ naa, ki Olubadan tuntun si ti wa lori itẹ lẹyin ti wọn ba ti pari eto gbogbo to yẹ, ẹjọ to wa ni kootu yii ni ko jẹ ki kinni naa ti ṣee ṣe lati ọjọ yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE  ṣe gbọ, awọn Central Council of Ibadan Indigene, iyẹn igbimọ to ga ju lọ fawọn ọmọ bibi ilu Ibadan (CCII), ni wọn petu si aigbọra-ẹni-ye to wa laarin Ladọja atawọn afọbajẹ yooku, ti baba naa fi gba lati gbe ẹjọ to pe wọn kuro nile-ẹjọ.

Nigba to n ṣalaye idi to ṣe pe ijọba ipinlẹ Ọyọ atawọn afọbajẹ ẹgbẹ ẹ lẹjọ lori ọrọ oye Olubadan, Ladọja sọ pe oun gbọ pe inu awọn eeyan naa ko dun si bi oun ṣe kọ lati jọba gẹgẹ bii awọn, nitori idi eyi, wọn fẹẹ sọ ọ dofin pe agba ijoye Ibadan ti ko ba ti kọkọ jọba na ko le jẹ Olubadan. Iyẹn ni pe Ladọja ko ni i le jọba nigba ti asiko ba to fun un lati gori apẹrẹ nla naa to ti n le lati nnkan bii ogoji (40) ọdun bọ wa.

Lara ohun ta a gbọ pe awọn CCII gbe siwaju Ladọja naa ni pe oun naa ni lati jọba gẹgẹ bii awọn akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu igbimọ Olubadan, ṣugbọn gomina tẹlẹ yii ko ti i fun wọn lesi, o ni ki wọn fun oun laaye lati ronu si ọrọ naa daadaa.

Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, ni bayii ti wọn ti gbẹjọ kuro ni kootu, ohun to ku bayii ni ki Gomina Makinde fọwọ si orukọ Ọlakulẹhin ti awọn afọbajẹ fi ranṣẹ si i, ki wọn si gbe ade ati ọpa aṣẹ fun baba naa gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

 

Leave a Reply