Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti kede pe iyawo oun, Olori Firdaus Akanbi, ti bimọ tuntun Obinrin lọmọ naa.
A oo ranti pe ọjọ kọkaninlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ni Oluwoo kede pe oun ti fi ọkan lara awọn Ọmọọbabinrin ilu Kano ọhun ṣe aya lẹyin ti Olori Chanel Chin kuro laafin.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, fi sita ni Ọba Akanbi ti sọ pe irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Olodumare fi ọmọ naa jinki idile oun.
O ni “Gbigbe ọmọ fun ọpọ oṣu ko rọrun. Mo ki Olori mi ku oriire ọmọ tuntun naa. Mo nigbẹkẹle kikun ninu eeso to ba ti inu rẹ jade. Ọmọ naa yoo ga, yoo si ṣe oriire ju mi lọ.
“Lẹẹkan si i, mo ki Olori mi, Firdaus, arẹwa obinrin to nitẹriba, to si nifẹẹ, ku oriire”