Faith Adebọla
Bi wọn ba n wa ẹnilọlobọ laarin awọn onitiata ilẹ wa lasiko yii, ẹnikan ti orukọ naa ba mu rẹgi ni Kẹmi Afọlabi, arẹwa oṣere-binrin kan to lọọ gba itọju lori ailera buruku to n dunkooko mọ ẹmi ẹ loṣu diẹ sẹyin. Kẹmi Afọlabi ti de o, awọn ololufẹ ẹ si ti n sọpẹ s’Eledua tori ẹmi to r’ẹmii.
Kẹmi funra ẹ lo fayọ kede ọrọ naa lori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ, lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii. O gbe fọto to ya ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ bo ṣe de Naijiria sori ikanni naa, irisi rẹ fa ni mọra, o rẹwa, o ri rente rente, ara rẹ si da ṣaka ju bo ṣe ri nigba to n rinrinajo lọ, o daju pe alaafia gidi ti to obinrin naa lagọọ ara.
Labẹ fọto naa lo kọ ọrọ si pe: “Mo ti de o, mo ti pada sorileede mi, Naijiria, ilu tẹru ẹ maa n ba mi gidi.”
Lẹyin eyi ni Kẹmi fi ẹdun ọkan rẹ han lori awọn ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria ati ipo ti orileede naa wa, o ni inu oun ko dun pe “lati papakọ ofurufu Muritala Mohammed lọọ de Oṣodi si Mowe, lọna marosẹ Eko s’Ibadan, sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ lo gba titi kan, eeyan o si ni i mọ ohun to ṣokunfa ẹ nigbẹyin.”
O sọrọ nipa titi ti ko daa, o si rawọ ẹbẹ si Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun lati ṣaanu awọn eeyan agbegbe Ọfada si Mowe, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.
Kẹmi ni bi inu oun iba ṣe dun to pe oun tun pada sile layọ lẹyin ọpọ akoko toun fi wa niluu oyinbo, o ni bi nnkan ṣe ri lorileede yii n kọ oun lominu.
Bi ọrọ ọhun ṣe gori ayelujara lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, atawọn ololufẹ ẹ ti n ba a yọ, wọn n ki i kuu oriire, ọpọ wọn lo si gba a lamọran lati fi ọrọ Naijiria sẹgbẹẹ kan na, wọn ni idunnu nla ni dide rẹ yii ja si, kọmọ ọlọpẹ yaa maa ṣọpẹ ni o.