Ọpẹ o, osere ilẹ wa, Dayọ Amusa, bimọ ọkunrin lanti lanti

Jọkẹ Amọri

Beeyan ba gẹṣin ninu arẹwa oṣere ilẹ wa to lomi lara daadaa nni, Temidayọ Amusa, tawọn ololufẹ rẹ tun maa n pe ni Dewumi Ibẹru, tọhun ko ni i kọsẹ rara, eyi ko sẹyin oore nla, oore ayọ,  t’Ọlọrun ṣẹṣẹ ṣe fun un. Oṣere naa ti bi ọmọkunrin lantilanti si orileede Amẹrika to wa bayii.

Ọpo eeyan ni oore ayọ naa ya lẹnu, nitori ko sẹni to ri oyun ninu rẹ ni gbogbo asiko to wa nipo iloyun. Pẹlu bo si ṣe maa n gbe fọto oriṣiiriṣii nibi to ti n ṣe faaji jade to, ko gbe aworan ibi to ti loyun si i, o fi kinni naa pamọ fun ọpọlọpọ eeyan, bẹẹ ni ko han loju rẹ ninu gbogbo awọn aworan ati fidio to ti gbe jade pe o ti di abarameji. Awọn to sun mọ ọn gbagbaagba bii iṣan ọrun nikan ni wọn mọ pe oṣere ti Wasiu Ayinde ti ki daadaa naa wa nipo iloyun.

Lọdun to kọja lo ti fi orileede Naijria silẹ, to ti lọ si Amẹrika, niṣe lawọn eeyan si ro pe o lọọ ṣe faaji nibẹ lasan, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe o ti ko lọ siluu oyinbo patapata nitori bi ọrọ aje Naijiria ṣẹ ri ni. Aṣe o ti wa ninu oyun ni gbogbo asiko naa.

Afi bo ṣe di ọsan ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ti oṣere yii gba ori ayelujara lọ, to si kọ ọ sibẹ pe, ‘’Alliamdulilahi, ọmọkunrin ni. Bi inu mi ṣe dun to ni inu yin paapaa dun yii, laipẹ ni ma a si maa pin ayọ ohun to ṣe iyebiye si wa yii pẹlu yin’’.

Ninu ọrọ rẹ lo ti tun sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe aworan ọmọ tuntun jojolo ti awọn eeyan n gbe sori ayelujara kiri ki i ṣe aworan ọmọ naa, o ni oun maa too gbe oju ikoko naa jade.

Latigba ti oore nla yii ti ṣẹlẹ si Dayọ Amusa ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ, awọn oṣere, atawọn afẹnifẹre ti n ki i ku ewu ọmọ, ti wọn si n rọjo adura le ọmọ tuntun t’Ọlọrun ṣẹṣẹ dun un yii lori.

Lara awọn to ti ki Dayọ ku oriire ni Tawa Ajiṣefinni-Alli, Damọla Ọlatunji, Toyin Abraham ati bẹẹ  bẹẹ lọ. Ọpọ awọn eeyan ti wọn nifẹẹ oṣere yii ni wọn ko le pa idunnu ayọ ọmọ tuntun ti Ọlọrun ṣẹṣẹ fun ọmọbinrin naa mọra, niṣe ni wọn n fo fayọ lori ayelujara.

Tẹ o ba gbagbe, igba kan wa ti awọn kan ti fi ọrọ ọmọ bu Dayọ, ti wọn ni ko lọ sile ọkọ, bẹẹ ni ko ye, ko si tun pa. Ṣugbọn Ọlọrun ti nu omije oṣere naa nu bayii pẹlu bo ṣẹ da a lohun, to si pese ọmọkunrin lantilanti fun un.

Gbogbo eeyan lo n ki iya ikoko bayii pe o ku ọwọ lomi

Leave a Reply