L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ṣafihan awọn afurasi mẹta kan, Peter Samuel, Jeremiah Tiozinda ati Sunday Agbenkẹ, ti wọn fẹsun kan pe wọn ge ori ọlọkada kan, Rafiu Akano, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn bọọlẹ lasiko ti wọn n gbiyanju lati gba ọkada lọwọ rẹ lagbegbe Asunlere, Òkè-Òyì, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, sọ pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, nigba ti awọn mẹta kan, Abdulrasheed Ọ̀la Sheu, Ismail Muhammad ati awọn miiran mu ẹsun wa sileesẹ ọlọpaa pe awọn ri ori eeyan kan ti wọn ti ge, tawọn ko si mọ ẹni to ge ori ọhun ati ẹni ti wọn ge ori ẹ lagbegbe Òkè-Òyì, niluu Ilọrin, tawọn agbofinro si ti lọọ gbe ori oku ọhun kuro lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo (UITH) ti Fasiti Ilọrin.
CP Ọlaiya ni nigba ti iwadii bẹrẹ lọwọ tẹ awọn afurasi mẹta kan lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, ni aaye ọtọọtọ, tawọn si ri foonu Android kan to jẹ ti Samuel Peter, eyi to n gbiyanju lati sa kuro niluu Ilọrin, ati ọkada kan gba lọwọ wọn, ti wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun, ati pe lẹbaa odo ni awọn ge ori ọlọkada naa si, nitori ki wọn le ta ọkada rẹ lati fi ri owo.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe agbẹ kan to n kọja lọ sinu oko rẹ ni awọn araalu n le, wọn le e de agọ ọlọpaa, wọn ni oun lo ṣeku pa ọlọkada naa, wọn si ba mọto rẹ jẹ. Bakan ni Ọlaiya ni lara awọn to ba mọto ọkunrin naa jẹ tọwọ tẹ ni Yusuf Abdulkareem, ẹni ọdun mejilelogun, Arabinrin Jaiyeọla Fatai, ẹni ogoji ọdun, atawọn miiran ti ọlọpaa ṣi n wa bayii.
Ọlaiya ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju awọn afurasi ọhun bale-ẹjọ.