Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ awọn agbofinro ti ipinlẹ Ondo ti pada tẹ afurasi ọdaran kan ti wọn porukọ rẹ ni Precious, ẹni ti wọn fẹsun kan pe oun lo wa nidii bi wọn ṣe ṣeku pa ọga rẹ, Abilekọ Mọsurat Debbie Ọlakunbi Adene.
Oloogbe ọhun lawọn ọmọọṣẹ rẹ meji, Philip Emmanuel, to jẹ amugbalẹgbẹẹ to gba lai ti i pe oṣu mẹfa, ati awakọ rẹ, Precious, ẹni ti ko ti i ju bii oṣu meji pere lọdọ rẹ pa mọ’nu ile rẹ, to wa loju ọna Ọda, niluu Akurẹ, lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2024 yii.
Awakọ ọhun ti wọn lo jẹ ọmọ bibi ilu Idanre, nipinlẹ Ondo, la gbọ pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ laarin ọsẹ ta a wa yii, lẹyin bii oṣu kan le diẹ ti wọn ti n dọdẹ rẹ.
Ọkunrin tọwọ tẹ ọhun ni wọn lo ṣi wa nikaawọ awọn ọlọpaa, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.
Philip to jẹ amugbalẹgbẹẹ Abilekọ Adene, lọwọ kọkọ tẹ ni kete ti iṣẹlẹ buruku naa waye, ṣugbọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣe afihan rẹ ni nnkan bii ọsẹ meji si asiko ta a wa yii.
Ohun ti Philip si n tẹnu mọ ju lọ ninu ifọrọwanilẹnu wo ti ALAROYE ṣe fun un nigba naa ni pe, Precious to jẹ awakọ Madaamu lo mu aba ki awọn pa a wa lẹyin to gbọ ti obinrin naa n ba ẹnikan sọrọ lori ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (#150,000), ti wọn sẹsẹ san sinu asunwọn banki rẹ.
Latigba t’ọrọ yii ti waye lawọn ọlọpaa ko ti sinmi rara, tọsan toru ni wọn fi n lepa rẹ, ti tọwọ wọn fi pada tẹ ẹ laipẹ yii.