Aderounmu Kazeem
Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu lo fi iroyin ayọ kan sita ni nnkan bii wakati meloo kan sẹyin, ohun to si sọ ni pe, arun koronafairọọsi ti n kasẹ nilẹ daadaa nipinlẹ Eko.
Nibi eto kan ti ijọ Kristẹni, Church of Nigeria, Anglican Communion, ṣe ni gbọngan Tafawa Balewa, Onikan, niluu Eko, lo ti sọrọ ọhun.
O ni ṣaaju asiko yii, iroyin to ba ni lẹru lo n tẹ ijọba lọwọ pe nigba to ba ya, niṣe ni wọn yoo maa ṣa oku ọpọ eeyan loju titi ni ipinlẹ Eko. Sanwo-olu waa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ohun tijọba gbọ niyẹn latari iwadii, ṣugbọn niṣe ni Ọlọrun ṣiju aanu wo ipinlẹ naa, ti wahala arun aṣekupani yii si ti bẹrẹ si ni i dinku daadaa, ti alaafia si ti n jọba l’Ekoo.
Gomina naa ko ṣai kaaanu awọn eeyan ti wọn padanu awọn mọlẹbi wọn ninu isẹlẹ naa, bakan naa lo ti ke si awọn ile ijọsin lati tubọ tẹra mọ adura ki ipinlẹ Eko ati Nigeria pẹlu gbogbo agbaye lapapọ le bọ lọwọ korona yii.
O ni bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ pe a ti bọ patapata, sibẹ lojoojumọ ni adinku n ba idaamu to n ko ba awọn eeyan, ti ireti to fẹsẹ mulẹ daadaa si wa wi pe niṣe ni itankalẹ aisan naa n dinku si i, ki i ṣe pe o n pọ si i.