Ọpẹ o, Wọn ti fun Pariolodo ni mọto olowo nla

Adewale Adeoye

Beeyan ba gun ẹṣin ninn gbajumọ oṣere tiata nni, Pariolodo, o daju pe tọhun ko ni i kọsẹ rara pẹlu bi inu rẹ ṣe n dun ṣinkin bayii.

Eyi ko sẹyin bi awọn ẹlẹyinju aanu kan ti wọn jẹ ọmọ orileede yii ṣe dawo jọ, ti wọn si ra ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn n pe ni ‘Toyota Camry 2014 Model’, fun un laipẹ yii.

Ọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni Pariolodo gba ẹbun mọto bọginni ọhun lati ọdọ ẹni to ba a ṣeto ikowojọ ọhun.

Nigba ti oṣere naa n ba ALAROYE sọrọ lori ọkọ tuntun tawọn ololufẹ rẹ fi ta a lọọrẹ yii lo ti so pe, ko sohun toun fẹẹ sọ ju pe koun ṣaa maa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu ẹbun naa lọ.

Pariolodo ni, ‘Loootọ ni pe wọn ti fun mi ni mọto o, ko sohun ti ma a ṣọ ju pe ki n maa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti Ọlọrun Ọba lọ fun aduru ẹbun yii lọ. O jẹ ohun kan to jọ mi loju gidi. Pe, emi paapaa le lo mọto nigbesi aye mi, mi o ro o rara, ṣugbọn ṣẹ ẹ waa ri ọna ara ti Ọlọrun Ọba gba yọ si mi bayii’

Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Pariolodo ṣe fidio oniṣẹju diẹ kan bayii sori afẹfẹ, nibi to ti n bẹ awọn araalu, paapaa ju lọ, awọn ololufẹ rẹ gbogbo nilẹ yii ati loke okun, ti wọn n gbadun ere rẹ lori awọn fiimu agbelewo gbogbo pe ki wọn dide iranlọwọ mọto foun naa. Pariolodo sọ oniruuru oke iṣoro to n la kọja lakooko yii ti ko fi ni mọto lati maa gun kaakiri aarin ilu Eko. Ko si pẹ rara ti awọn ẹlẹyinju aanu kan ti wọn jẹ ọmọ orileede yii fi dawo jọ fun un, ti wọn si ti ra mọto bọginni kan bayii fun un.

Lati ori oṣẹrebinrin, Iya Gbonkan, ni wọn ti kọkọ bẹrẹ, to fi dori Lalude, bakan naa ni Pariolodo paapaa ti ri ojurere awọn ololufẹ rẹ gba bayii. Yatọ si mọto ti wọn fi ta a lọrẹ yii, wọn tun ba a tun ile rẹ to n kọ lọwọ ṣe debi to lapẹẹrẹ, ti wọn  si tun ṣe awọn ohun mere-mere miiran fun.

Gbogbo eyi ni oṣere alawada ọhun ro papọ to fi n dupẹ gidi lọwọ awọn araalu ti wọn dawo jọ fun un bayii atawọn ololufẹ rẹ gbogbo.

Leave a Reply