Faith Adebọla
Bi ohun gbogbo ba lọ bi wọn ṣe gbero rẹ, ipinlẹ Ogun ko ni i pẹẹ dara pọ mọ awọn ipinlẹ ti wọn ti n wa epo rọbi lorileede yii. Ijiroro ati asọye gidi si ti n lọ lori rẹ, koda, ọrọ naa ti n de ikorita adehun ati ibuwọ-luwe, ti iṣẹ yoo si bẹrẹ ni pẹrẹu laipẹ.
Gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii nigba to n gbe aba eto iṣuna owo ipinlẹ ọhun fun ọdun 2024 to wọle de tan yii kalẹ siwaju awọn aṣofin ipinlẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.
Ninu bọjẹẹti to ka fawọn aṣofin ọhun, eyi to pe akọle rẹ ni ‘Bọjẹẹti fun itẹsiwaju ati idagbasoke ti ko ni i duro’ ni gbọngan apero ileegbimọ wọn to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, Gomina Abiọdun ni, “ijiroro ti n lọ ni rẹbutu nipa bi wọn ṣe maa bẹrẹ si i wa epo rọbi ni Erekuṣu Tọngeji, to wa nijọba ibilẹ Ipokia, ati ni Olokola, to wa nijọba ibilẹ Ogun Waterside. A ni igbọkanle pe laipẹ, ti ko ni i jinna rara, ipinlẹ Ogun naa yoo darapọ mọ awọn ipinlẹ to n pese epo rọbi lorileede yii.”
Gomina naa fi kun un pe lara igbaradi ti ijọba oun ti ṣe lati mu ki eto ọhun kẹsẹjari ni bi oun ṣe ṣedasilẹ ẹka ileeṣẹ to n ri si ohun alumọọni nipinlẹ Ogun, iyẹn Ministry of Mineral Resources, toun si fa iṣẹ le wọn lọwọ lati ṣamojuto gbogbo eto ati akoso to jẹ mọ ti nnkan alumọọni loriṣiiriṣii ti Ọlọrun fi jinki ipinlẹ Ogun.
Bakan naa lo ni iṣakoso oun tun ṣagbekalẹ ẹka to n mojuto awọn nnkan amuṣagbara, iyẹn Ministry of Energy, ki wọn le wo bi wọn yoo ṣe fi ẹsẹ ofin tọ ọrọ ọhun nibaamu pẹlu awọn atunṣe to wa ninu iwe ofin ilẹ wa, eyi to fawọn ipinlẹ ati aladaani laaye lati kopa ninu ipese epo rọbi.
L’Ọjọbọ ọhun, aba eto iṣuna oni-biliọnu lọna ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin Naira (N703 billion), ni Ọmọọba Dapọ Abiọdun sọ pe ipinlẹ Ogun yoo na lọdun 2024 yii.