Ọpẹyẹmi Bamidele di olori ọmọ ile to pọ ju lọ nileegbimọ aṣofin agba

Monisọla Saka

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun Ekiti, nipinlẹ Ekiti, Michael Ọpẹyẹmi Bamidele, ti di olori awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba to pọ ju lọ l’Abujaa.

Bakan naa ni wọn kede Sẹnetọ Dave Umahi, to n ṣoju apa Guusu ipinlẹ Ebonyi, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ naa ri gẹgẹ bii igbakeji olori ọmọ ile to pọ ju lọ. Sẹnetọ Ali Ndume, to n ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Borno, lo di ipo ọlọpaa ile mu, nigba ti Sẹnetọ Lọla Ashiru lati ipinlẹ Kwara, yoo maa ṣe igbakeji fun un.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun yii, ni Godswill Akpabio, ti i ṣe olori ileegbimọ aṣofin kede ọrọ naa lasiko ijokoo ile.

Ṣaaju igba naa ni wọn ti ni Akpabio ṣepade idakọnkọ pẹlu awọn eeyan ọhun, lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ti mu orukọ wọn kalẹ gẹgẹ bii ẹni to kunju oṣuwọn fawọn ipo yii.

Leave a Reply