Monisọla Saka
Ko din ni ogun eeyan, ti pupọ ninu wọn si jẹ obinrin ati ọmọde, ti wọn dagbere faye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun yii, lẹyin ti ọkọ oju omi onigi ti wọn wọ doju de lagbegbe Ocholonya, niọba ibilẹ Agatu, nipinlẹ Benue.
Ilu Odenyi, to wa nijọba ibilẹ Nasarawa Toto, nipinlẹ Nasarawa, ni wọn lawọn ọlọja naa n lọ lẹyin ti wọn naja Ocholonya tan, nigba ti wọn nijamba to mu ẹmi wọn lọ yii.
Adanyi, to jẹ ọkan lara awọn araalu naa to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe “Ọjọ Abamẹta, Satide, ni ọjọ ọja Ocholonya, ninu ijọba ibilẹ Agatu yii kan naa si ni.
“Awọn eeyan to jẹ pe obinrin atawọn ọmọde lo pọ ninu wọn yii n dari pada lọ si adugbo tiwọn niluu Odenyi, nipinlẹ Nasarawa, ni ọkọ oju omi to n gbe wọn lọ yi danu, ti gbogbo wọn si ba iṣẹlẹ ọhun lọ”.
Ọgbẹni Melvin James, ti i ṣe alaga ijọba ibilẹ Agatu, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni, “Bẹẹ ni, loootọ ni iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi waye lọjọ Satide, ọja Ocholonya, lawọn eeyan yẹn waa na. Inu ijọba ibilẹ Agatu ni Ocholonya wa.
“Nnkan temi gbọ ni pe nigba ti wọn n pada sibi ti wọn ti wa niluu Apochi ati Odenyi, lagbegbe Doma, nipinlẹ Nasarawa, ni ọkọ oju omi wọn danu sinu agbami.
“Mo ti n gbiyanju lati ba ojugba mi lati ipinlẹ Nasarawa sọrọ, lati le mọ bi a ṣe le yọju sawọn mọlẹbi awọn tiṣẹlẹ naa ṣẹ si, ki a le ba wọn kẹdun.
Oriṣiiriṣii awuyewuye ni mo ti gbọ, wọn ni awọn eeyan bii ogun ni wọn ku, ṣugbọn emi o ti i gbọ pe wọn ti ri oku wọn yọ jade.
“Bakan naa lawọn araalu sọ pe awọn omuwẹ ti ri awọn oku kan gbe jade, amọ gẹgẹ bii alaga, aṣẹ ni mo gbọdọ fi sọrọ pẹlu aridaju. Mo fẹẹ ba awọn omuwẹ yẹn naa sọrọ lati le mọ iye oku ti wọn ri gbe jade, ṣugbọn nọmba ibanisọrọ wọn ko lọ.
“Amọ ohun tẹnikan sọ fun mi ni pe oku bii ogun ni wọn ti ri gbe jade, ti wọn ko si ti i ri awọn yooku”.
O sọrọ siwaju si i pe, gbogbo akitiyan lawọn n ṣe, ati pe oun ti ba olori awọn ọmọ ogun oju omi (Nigerian Navy), ẹka ti agbegbe naa sọrọ, lati kun wọn lọwọ lori bi wọn yoo ṣe ri oku to ṣẹku sinu omi ko jade.
Ka ranti pe, ọpọlọpọ iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi lo ti ṣẹlẹ laarin oṣu mẹta si asiko yii lagbegbe Benue, Niger ati Kogi, eyi to mu ki ẹgbẹ akẹkọọ awọn ileewe gbogboniṣe lorileede yii, ẹka tipinlẹ Kogi, rọ ijọba lati ko awọn ọkọ oju omi onipako kuro nilẹ, ki wọn pese ti igbalode fun awọn eeyan ipinlẹ ti omi wa lati le daabo bo ẹmi wọn.