Monisọla Saka
Ijamba buburu niṣẹlẹ to waye lagbegbe Papa Ajao, Mushin, nipinlẹ Eko, lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, pẹlu bi mọṣalaṣi kan ṣe wo lulẹ lasiko tawọn Musulumi n kirun ọsan lọwọ.
Ko sẹni to ti i le sọ ohun to fa a ti mọṣalaṣi naa fi wo lojiji, ọpọlọpọ ẹmi ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ọpọ lo ti ha sabẹ awoku ile naa, ti awọn eeyan to wa nitosi n gbiyanju lati yọ wọn jade.
ALAROYE gbọ pe lasiko ti wọn n kirun lọwọ gan-an, tawọn ero si pọ ninu ile ijọsin naa, lo da wo lulẹ, eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi ku, ti pupọ awọn ti ko tete ribi sa asala fẹmi-in wọn si fi ha si abẹ awoku ile naa.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ lọwọ, ko ti i si atẹjade kankan lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, Lagos State Emergency Management Authority (LASEMA), lati le fidi ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ buburu yii mulẹ, ati ọna abayọ yoowu ti wọn ti ri si i.