Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ṣe ni ọpọ fara pa, ti wọn si ba ọkẹ aimọye dukia jẹ lasiko tawọn gende-kunrin kan lagbegbe Adeta ati Isalẹ-Jagun, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, n ja lori obinrin kan lati ọjọ Aiku, Sunnde, ọṣẹ yii, titi di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii.
ALAROYE, gbọ pe rogbodiyan naa bẹrẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni otẹẹli kan to wa ni agbegbe Adewọle, niluu Ilọrin. Lasiko ti wọn n ṣe pati alẹ nibẹ ni ọdọkunrin kan ti wọn forukọ bo laṣiiri ri aburo rẹ obinrin to ti sa nile lati bii ọjọ meloo kan sẹyin. Lo ba paṣẹ fun aburo ẹ yii pe ko fi agbegbe naa silẹ kiakia, ko maa lọ sile.
Eyi ko dun mọ ọkunrin to gbe ọmọbinrin ọhun wa si ileejo ninu, ọrọ naa lo si di wahala laarin ọkunrin to gbe ọmọbinrin naa wa ati ẹgbọn rẹ.
Ọmọkunrin yii lo ko awọn janduku lọ sile awọn ọmọbinrin naa lati lọọ gbẹsan ohun ti ẹgbọn rẹ ṣe, lo ba dija adugbo-si-adugbo, ni wọn ba bẹrẹ si i ba dukia ara wọn jẹ. Gbogbo awọn mọto ati kẹkẹ Maruwa to wa ni gbogbo ayika awọn mejeeji ni wọn fọ, ti ọpọ si tun fara gbọta ibọn ati igo pẹlu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọwọ ti tẹ mẹta ninu awọn janduku ọhun, awọn si ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin (UITH), to wa ni Oke-Oyi, fun itọju to peye.