Opo to n pin ina fun gbogbo Naijiria ti tun daṣẹ silẹ o

Monisọla Saka

Opo to n pin ina fun gbogbo ilẹ Naijiria tun ti daṣẹ silẹ. Lati alẹ ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni gbogbo Naijiria tun ti wa ninu okunkun.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, ni nnkan bii aago meji ọsan ku iṣẹju mọkanlelogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu yii, ni agbara ina naa lọ silẹ patapata.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣẹju ina naa ni nnkan bii aago mẹfa kọja laaarọ ọjọ Tusidee yii, nigba ti yoo fi di aago meji si mẹta ọsan, agbara to n gbe ina kiri ti lọ tan yan-an-yan.

Ninu atẹjade ti wọn ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lorilẹ-ede yii, Transmission Company of Nigeria (TCN), fi sita lati fidi ọrọ yii mulẹ ni wọn ti ni, “Nnkan kekere kan ṣe opo nla to n pin ina fun gbogbo Naijiria ni nnkan bii aago meji ọsan ku iṣẹju mẹjọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu yii”.

Ndidi Mbah, ti i ṣe agbẹnusọ ileeṣẹ TCN, sọ pe,” Eleyii waye latari waya to n ja, atawọn to n fi ina jẹnẹretọ ti wọn n tan ba waya jẹ, eyi lo fa a ti opo ina naa fi bẹrẹ si i ṣe ṣegeṣege, to si fi di eyi to n yọ ọ lẹnu diẹdiẹ, ti ina fi lọ”.

Arabinrin Ndidi ni ayẹwo tawọn ṣe nibudo ti wọn ti n dari ina, National Control Centre, fi han pe ina to lọ yii ko pa awọn apa kan lara.

“Awọn onimọ ẹrọ ileeṣẹ TCN ti n ṣiṣẹ lori bi wọn ṣe le tete da ina pada sawọn ipinlẹ ti o pa lara. Lọwọlọwọ bayii, wọn ti da ina pada siluu Abuja, ni aago mẹta ọsan ku iṣẹju mọkanla, bẹẹ la ti n ṣe e wẹrẹwẹrẹ lati da a pada sawọn apa ibomi-in lorilẹ-ede yii”.

O waa bẹ awọn eeyan, paapaa ju lọ awọn onibaara wọn, pe awọn tọrọ aforiji fun inira yoowu ti ina to lọ naa ti le ko ba wọn.

Ka ranti pe ẹẹmẹta ọtọọtọ ni opo ina yii kọṣẹ, ti gbogbo Naijiria si wa ninu okunkun fun aimọye ọjọ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Leave a Reply