Jide Alabi
Gomina Rotimi Akeredolu ti bu ẹnu atẹ lu bi Amofin Eyitayọ Jẹgẹdẹ ṣe kọwe sileeṣẹ ọlọpaa pe awọn eeyan kan fẹẹ pa oun, nitori ti oun gbe ọrọ ibo gomina ipinlẹ Ondo lọ sile-ẹjọ.
Laipẹ yii ni oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ, kegbajare pe oriṣiiriṣii ipade lawọn eeyan kan n ṣe lati fi gbẹmi oun, nitori ti oun gba ile-ẹjọ lọ, lati ta ko esi ibo to gbe Akeredolu wọle pada gẹgẹ bii gomina.
Ni kete to sọrọ yii lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti kẹnu bo o, ti wọn si sọ fun un pe ko sẹnikan bayii to ri tiẹ ro mọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ati pe ẹgbẹ naa ko lepa ẹmi ẹnikẹni.
Wọn ni idaamu to de ba Eyitayọ Jẹgẹdẹ lori bi Rotimi Akeredolu, ṣe wọle lẹẹkan si i lo ṣi n da ọkan ẹ ru, ati pe iyẹn gan-an lo fa a to fi n wa ohun ti ko sọnu kiri.
Ninu ọrọ ti Oluranlọwọ fun Eyitayọ Jẹgẹdẹ nipa eto iroyin, Ọgbẹni Gbenga Akinmọyọ, kọ sileeṣẹ ọlọpaa lo ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP fẹẹ fi asiko yii sọ fun awọn ẹṣọ agbofinro pe niṣe lawọn eeyan kan n lepa ẹmi ọkunrin oloṣelu naa kiri.
Bakan naa lo tun sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP nigbagbọ pe niwọn igba ti awọn ti kegbajare ọrọ ọhun sita bayii, ileeṣẹ ọlọpaa yoo gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.
Loju ẹsẹ tọrọ yii ti jade naa lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti fesi, ohun ti wọn si sọ ni pe o maa dara ki Eyitayọ Jẹgẹdẹ kọju mọ awọn iwe irọ to ko jọ, to loun fẹẹ lo niwaju igbimọ ti yoo gbọ ẹsun oriṣiiriṣii lori eto ibo gomina, dipo awuyewuye irọ to fẹẹ da silẹ yii. Wọn ni bo tilẹ jẹ pe yoo kuna lori ẹjọ to pe ọhun, sibẹ niṣe lo tun n wa ọna oriṣiiriṣii mi-in to fẹẹ fi da ipinlẹ ọhun ru.
Wọn ni Jẹgẹdẹ ko ṣẹṣẹ maa parọ kiri, ati pe eyi to tun fẹẹ bẹrẹ ẹ yii, ariwo lasan ni, ko sẹnikẹni to ni in lọkan lati ṣe aburu kan bayii fun un.
Ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe lati ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, lawọn eeyan wọn ti dibo yan ẹni ti ilu n fẹ, ati pe asiko yii gan-an lo yẹ ki Jẹgẹde gba fun Ọlọrun, ko yee wa ohun ti ko sọnu kiri.
Wọn ni bo ṣe fẹẹ maa fi iroyin ijaya yii wa aanu awọn araalu sọdọ ara ẹ ki i ṣe ohun to bo bojumu rara.