Ko si bawọn eeyan Bekaji ati Karewa, l’Adamawa, ni Yola, yoo ṣe gbagbe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii. Ọjọ naa ni marun-un ninu awọn gende ọkunrin wọn jona ku ninu ijamba mọto, nigba ti wọn n lọ sibi idana ọrẹ wọn kan.
Ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ Gomina ipinlẹ Adamawa, Ọgbẹni Miracle Musa, ṣalaye pe Kaduna lawọn ọkunrin marun-un ti wọn jẹ ọrẹ ọkọ naa n lọ, ọrẹ wọn kan lo n ṣe idana lọjọ naa.
Mẹta ninu awọn ọkunrin yii jẹ ọmọ Bekaji, awọn meji wa lati Karewa GRA, l’Adamawa, kan naa.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ohun kan ti a gbọ ni pe niṣe ni mọto ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu ẹ gbina lojiji, awọn maraarun si jona kọja idanimọ.
Ṣa, wọn darukọ meji ninu wọn, orukọ wọn ni Saddam Aje Shinguboi ati Mwaniya Japhet Gajere.
Bẹẹ lo si ṣe ti baale ile marun-un dero ọrun lojiji, lọjọ ti wọn fẹẹ lọọ ba ọrẹ wọn ṣẹyẹ ni Kaduna.